Ọlawale Ajao, Ibadan
Ọwọ ti tẹ awọn oṣiṣẹ ijọba ipinlẹ Ọyọ ti wọn ji ounjẹ to yẹ ki ijọba pin fawọn araalu gẹgẹ bii ohun iranwọ lasiko ajakalẹ arun Korona ko.
Awọn oṣiṣẹ ijọba wọnyi ta a forukọ bo laṣiiri, ni wọn mu awakọ ero kan nigboro Ibadan mọra lati ji aadọrin (70) gbe ninu awọn apo agbado ti ìjọba Gomina Ṣeyi Makinde gbero lati fi ran awọn ti ebi n pa ni ipinlẹ naa kuro ninu ajaga ebi.
Inu ọkọ nla kan pẹlu ọkọ ayọkẹlẹ meji ni wọn ko awọn agbado ọhun si lati lọọ ta fawọn oniṣowo ounjẹ lọja.
Ni ibamu pẹlu ibeere awọn agbofinro to n ṣọ oju ọna naa, awọn oṣiṣẹ ijọba wọnyi sọ pe ọga to wa nidii akoso ẹru ti wọn ko pamọ naa lo ni ki awọn ko o jade lati pin in fawọn araalu.
Njẹ iwe aṣẹ ti ọga ọhun fun yin lati gbe awọn ẹru wọnyi kuro nibi ti wọn ko o pamọ si da, niṣe lawọn oṣiṣẹ ijọba naa n fọwọ ra ori. Nigba naa lawọn agbofinro fi panpẹ ọba gbe wọn lọ satimọle atawọn tẹru ijọba ti wọn ji ko, ati mọto mẹtẹẹta ti wọn ko wọn si.
Nigba to n ṣafihan awọn afurasi ole naa fawọn oniroyin n’Ibadan, ọga agba ajọ Sifu Difẹnsi ni ipinlẹ Ọyọ, Ọgbẹni Isikilu Akinsanya, sọ pe oṣiṣẹ ajọ to n mojuto igbokegbodo awọn ohun irinṣẹ ni ipinlẹ yii lawọn afurasi ole naa nigba ti ẹni kẹrin wọn jẹ awakọ ero nigboro.
O ni “O pẹ ta a ti n gbọ pe wọn n ji awọn ẹru iranwọ fawọn araalu lasiko Korona ko ninu Sẹkiteriati, ta a si ti n ṣọ awọn to n ṣiṣẹ buruku naa ko too di pe Ọlọrun fun wa laṣeyọri ṣe lọjọ Wẹsidee.
“Ara nnkan ta a maa n sọ niyẹn. Ijọba yoo maa lakaka lati ṣe ohun to maa jẹ ki awọn araalu gbe igbe aye irọrun, awọn araalu kan yoo si
maa ba akitiyan ijọba jẹ. Iru ẹ lawọn ti wọn ji ounjẹ ti ijọba fẹẹ pin fawọn araalu ko wọnyi”.
Ọga ajọ Sifu Difẹnsi yii ti waa ṣeleri lati gbe awọn afurasi ole yii lọ sí kootu ki wọn le jiya ẹṣẹ wọn labẹ ofin.