Eyi ni idi ti a ko fi lọ sibi ipade awọn agbaagba ẹgbẹ APC l’Ekoo-Fayẹmi, Akeredolu

Faith Adebọla

Gomina ipinlẹ Ekiti, Dokita Kayọde Fayẹmi, ati ẹlẹgbẹ rẹ nipinlẹ Ondo, Oluwarotimi Akeredolu, ti ṣalaye ohun to fa a ti wọn ko fi si nibi ipade pataki kan tawọn agbaagba ẹgbẹ APC nilẹ Yoruba ṣe, lọjọ Aiku, Sannde yii, niluu Eko.

Ninu atẹjade kan ti Akọwe iroyin gomina Ekiti, Yinka Oyebọde, fi sita, bi wọn ṣe pe ọga fun ipade naa tẹwọn to, nitori amugbalẹgbẹẹ Bọla Tinubu feto iroyin, Ọgbẹni Tunde Rahman, lo kan fi ọrọ kan ṣọwọ lori atẹ Wasaapu gomina ọhun.

O ni nigba tawọn fi maa gbọ hulẹhulẹ ipade naa, ko ṣee ṣe fun gomina lati pesẹ mọ tori wọn ti ṣeto ipade mi-in to pọn dandan fun un lati lọ.

O ni Fayẹmi fi ọrọ ranṣẹ sawọn to ku nipade ọhun, o ran Ọtunba Niyi Adebayọ lati ba oun tọrọ aforiji.

“Ẹni to nifẹẹ ijọba awa-ara-wa ni Fayẹmi, bẹẹ lo si nifẹẹ iṣọkan orileede yii, tori naa, gbogbo ipinnu ti wọn ṣe nipade naa lo fara mọ.”

Bakan naa ni Rotimi Akeredolu sọ ninu atẹjada kan ti Akọwe iroyin rẹ, Richard Ọlatunde, fi lede lọjọ Aje, pe idi toun ko fi pesẹ ni aigbọ agbọye nipa iwe ipe ti wọn fi ṣọwọ soun nipa ipade naa.

O ni ipade to bọ sakooko ni, iba si wu oun lati wa nibẹ, bi ko ba si ti pe oun ti ṣeto lati wa niluu Ibadan fun eto pataki mi-in, nigba ti atẹjiṣẹ ti wọn fi ṣọwọ nipa ipade ọhun ko kun to.

Akeredolu ni oun nigbagbọ ninu gbogbo ipinnu to ba maa ṣe ilẹ Yoruba ati orileede Naijiria lanfaani, oun si fara mọ awọn koko ti wọn fẹnu ko le lori nipade yii.

Leave a Reply