Eyi ni idi ti mo fi yan Okowa ni igbakeji mi-Atiku

Ọrẹoluwa Adedeji
Oludije funpo aarẹ ninu ẹgbẹ oṣelu PDP, Alaaji Atiku Abubakar ti sọ idi to fi yan Gomina ipinlẹ Delta, Ifeanyi Okowa gẹge bii ẹni ti yoo ṣe igbakeji rẹ.
O sọrọ yii lẹyin ti wọn fa ọwọ ọwọ Okowa soke gẹgẹ bii ẹni ti yoo dije pẹlu rẹ.
Atiku ni idi ti oun fi yan ọkunrin naa ni igbakeji oun ni pe, oun ti ni i lọkan pe iru ẹni bẹẹ ṣee ṣe ko gba ipo naa lọwọ oun lọjọ iwaju. Ati pe ẹni to ni amuyẹ lati di aarẹ Naijiria ni oun gbọdọ yan si iru ipo bẹẹ. Ẹni ti yoo loye iru ipo ibajẹ ti ẹgbẹ APC ti fi Naijiria si, ti yoo si loye idaamu ati wahala to n ba awọn eeyan orileede yii finra, ati ohun to pe fun lati tete yọ wọn jade niru ọfin bẹẹ kiakia.
Iru ẹni bẹẹ gbọdọ mọ pataki eto ẹkọ lati le ṣe igbelarugẹ awujọ tuntun ti ode oni pe fun, leyii ti a oo fi pese awọn ọmọ wa, ti wọn yoo si mura silẹ lati le maa figagbaga pẹlu awọn ẹlẹgbẹ wọn kaakiri agbaye gẹgẹ bi Atiku ti wi.
‘‘Ẹni ti yoo jẹ igbakeji mi gbọdọ mọ pe lai si eto aabo to peye, yoo nira lati ni idagbasoke, nitori awọn olokoowo ilẹ okeere ti ẹru ti n ba, ti wọn si ti lọ ko ni i le pada wa lati waa da si ọrọ aje wa. Nitori idi eyi, ẹni ti yoo jẹ igbakeji mi gbọdọ jẹ ẹni ti yoo duro ti mi bi mo ṣe n koju eto aabo to ba ni lẹru jọjọ to n koju orileede wa.
‘‘Ẹni ti yoo jẹ igbakeji mi gbọdọ ni igboya lati le sọ tẹnu rẹ, ti yoo si fun mi ni imọran to tọ, ti yoo si wa ni ẹgbẹ mi bi mo ṣe n ṣiṣẹ takuntakun lati da gbogbo ohun ti ẹgbẹ APC ti bajẹ laarin ọdun meje ti wọn ti wa nijọba yii pada bọ sipo.’’
Atiku fi kun un pe yiyan igbakeji yii ki i ṣe iṣẹ oun nikan, awọn gomina ẹgbẹ naa, awọn alẹnulọrọ, awọn agbaagba ẹgbẹ, igbimọ majẹ-o-bajẹ lo ni wọn kora jọ lati ṣe ipinnu yii.
O ni o ṣe pataki ki ẹgbẹ naa wa ni iṣọkan. Atiku ni wiwa ni iṣọkan yii ko ni i wa fun lati ṣe agbekalẹ eto ipolongo nikan, bi ko ṣe lati pese eto ijọba to daa ti orileede wa nilo lasiko yii, eyi ti awọn eeyan wa si n poungbẹ fun.
Bakan naa lo gboriyin fun awọn ọmọ ẹgbẹ naa ti wọn jọọ dupo lati ṣoju ẹgbẹ wọn lasiko eto idibo abẹle. O ni awọn eeyan naa ja takuntakun, eyi si waye nitori pe wọn nifẹẹ orileede Naijiria lọkan ni. Atiku ni oun ti ṣabẹwo si gbogbo wọn, ti oun si ti dupẹ lọwọ wọn, bẹẹ loun beere fun ifọwọsowọpọ wọn.
Gomina ipinlẹ Rivers, Nyesome Wike, ati Gomina Delta ti wọn mu ni igbakeji Atiku yii, Ifeanyi Okowa, ni awọn eeyan ti n gbe pooyi ẹnu pe o ṣee ṣe ki ọkan ninu wọn jẹ ẹni ti wọn yoo yan ni igbakeji Atiku.

Leave a Reply