Faith Adebọla
Ọlọgọmbọ ti ilẹ Ọgọmbọ, to wa nijọba ibilẹ Eti-Ọsa, nipinlẹ Eko, Ọba Muslim Abiọdun Ogunbọ, Ogudu Ọshadi ti ilẹ Ọgọmbọ, ti ki awọn ọmọ Naijiria, paapaa ju lọ awọn eeyan ipinlẹ Eko, ku oriire aṣeyọri eto idibo sipo aarẹ, awọn gomina ati tawọn aṣofin to waye, nibi ti awọn ọmọ orileede yii ti yan awọn ti yoo maa dari wọn.
Ninu atẹjade kan ti ọba alaye naa fi ranṣẹ si ALAROYE nipasẹ Akọwe iroyin rẹ, Abayọmi Gbelẹyii, lo ti dupẹ lọwọ Ọlọrun ati awọn alalẹ pe eto naa yọri si rere lai si itajẹsilẹ tabi wahala kankan.
Ọba Abiọdun Ogunbọ ṣalaye pe ọkan ọpọlọpọ araalu lo ko soke ki eto idibo naa too waye, nitori oriṣiiriṣii asọtẹlẹ ati ihale tawọn kan n ṣe lori idibo ọhun, ṣugbọn pẹlu rẹ naa, Ọlọrun da si eto naa, bẹẹ lawọn alalẹ naa ko sun, wọn ko si jẹ ki awọn asọtẹlẹ ibi ti ọpọ eeyan ti sọ lori eto idibo ọhun wa si imuṣẹ.
Bakan naa lo lu awọn araalu lọgọ ẹnu lori ipinnu wọn lati dibo, ki wọn si yan ẹni to wu wọn sipo pẹlu bi gbogbo nnkan ko ṣe fara rọ, ti nnkan ko si dẹrun lasiko ti eto idibo naa waye.
Ọba Ọgọmbọ ni eyi ti ọrọ owo Naira da silẹ ninu ọrọ naa ko kere, nitori ọpọ araalu ni ko rowo na, ti ohun gbogbo si dẹnu kọlẹ, ṣugbọn pẹlu re naa, awọn eeyan jade lati dibo yan ẹni to ọkan wọn fẹ, ohun gbogbo si lọ ni irọwọ-rọsẹ lai si itajẹsilẹ.
Kabiyesi waa ki aarẹ aarẹ tuntun ti wọn ṣẹṣẹ dibo yan, Aṣiwaju Bọla Ahmed Tinubu, ẹni to ṣapejuwe gẹgẹ bii ogo ati irawọ ti yoo tan imọlẹ alaafia ati idagbasoke si gbogbo ilẹ Yoruba ati gbogbo Naijiria lapapọ.
Kabiyesi ni, ‘‘Mo mọ pe iyansipo Aṣiwaju Bọla Tinubu ni ọwọ Ọlọrun ninu, o si ni ohun ti Ọlọrun fẹẹ lo o fun ni ilẹ Yoruba, ati ilẹ Naijiria lapapọ. Ẹmi ọgbọn, oye, alaafia ati okun ni ka maa gbadura rẹ fun aarẹ wa tuntun yii, ki o le tukọ Naijiria de ebute alayọ nigba ti iṣejọba rẹ ba bẹrẹ.’’
Bakan naa lo ki Gomina ipinlẹ Eko, Babajide Sanwoolu, Igbakeji rẹ, Ọbfẹmi Hamzat. Ọba Ogunbọ ni yiyan ti wọn yan Sanwoolu ati igbakeji rẹ sipo jẹ igbagbọ ti wọn ni ninu ọkunrin naa ati iṣẹ rere to n ṣe nipinlẹ Eko, eyi ti wọn fẹ ko maa tẹsiwaju.
Bakan naa lo ki Wasiu Sanni Ẹṣinlokun ti wọn ṣẹṣẹ dibo yan gẹgẹ bii aṣofin agba, Olori awọn aṣofin ipinlẹ Eko, to tun wọn ṣẹṣẹ tun yan pada sipo, Mudaṣiru Ọbasa atawọn aṣofin ẹlẹgbẹ rẹ bii Noheem Adams, Gbọlahan Yishawu ati Ganiyu Ọkanlawọn Sanni.
O waa rọ awọn eeyan naa lati fi ifẹ awọn eeyan to dibo yan wọn ṣiwaju ohunkohun ti wọn ba fẹẹ ṣe.
Adura ni Kabiyesi fi kadii ọrọ rẹ nilẹ fun wọn pe aṣeye ti alakan n ṣepo lawọn eeyan naa yoo ṣe, ati pe itura ni ijọba Bọla Tinubu ti yoo bẹrẹ laipẹ yoo mu ba tolori tẹlẹmu ni Naijiria.