Nibi ti Fatai ti n sa koro kaṣu lawọn ajinigbe ti ji oun atọmọ ẹ mẹta gbe ni Kwara 

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Awọn afurasi ajinigbe kan ti ṣakọlu si arakunrin kan ti orukọ rẹ n jẹ Fatai, atawọn ọmọ rẹ keekeeke meji, AbdulBasit ati Ramọta, loko kasu ni opopona to lọ lati Aboto-Ọja si Ajelanwa, nijọba ibilẹ Asa, nipinlẹ Kwara, ni wọn ti lọọ ji wọn gbe lọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii.

Arakunrin Fatai, to ba oniroyin sọrọ sọ pe ni nnkan bii aago mẹji ọsan ọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii, ni awọn ajinigbe naa waa ba oun ninu oko toun ti n ṣa kaju, iro ẹsẹ lo ni oun n gbọ, ṣugbọn nigba ti oun gbe oju soke loun ri awọn ajinigbe mẹfa kan pẹlu ibọn Ak-47, ti oun si bẹrẹ si i sa lọ sọna Aboto-Ọja, to si fi awọn ọmọ rẹ keekeeke mẹta silẹ sinu ọkọ ayọkọlẹ rẹ.

O tẹsiwaju pe oun pada mori bọ, ṣugbọn wọn ji awọn ọmọ oun mẹtẹẹta ko lọ. Fatai ni nigba ti oun sa lọ loun pade baba kan to n ta ẹyin, ọkọ baba ẹlẹyin yii loun wọ, to si gbe oun lọ si Aboto-Ọja, bayii ni ori ṣe ko ọmọkunrin naa yọ lọwọ awọn ajinigbe.

O rọ ijọba Kwara, labẹ isejọba Gomina AbdulRazaq, ko doola ilu Aboto ati gbogbo agbegbe rẹ lọwọ awọn ajinigbe ti wọn soro bii agbọn.

Leave a Reply