Ẹ fagi le eto idibo yii ka di omi-in, Peter Obi bẹ ile-ẹjọ to n gbọ ẹsun idibo

Ọrẹoluwa Adedeji

Lọjọ Iṣegun, Tusidee, ọjọ kọkanlelogun, oṣu Keji yii, ni ẹgbẹ oṣelu Labour ko iwe ẹsun wọn lori eto idibo to kọja yii lọ sile-ẹjọ to n gbọ awọn ẹsun to ba su yọ lori eto idibo, eyi to fikalẹ siluu Abuja.

Lara awọn ẹbẹ ti oludije sipo aarẹ lorukọ ẹgbẹ oṣelu Labour Party, Peter Obi, bẹ ile-ẹjọ yii ni pe ki wọn fagi le eto idibo to waye lọjọ kẹẹẹdọgbọn, oṣu Keji, ọdun yii, nibi ti ajọ eleto idibo ti kede oludije lẹgbẹ APC, Bọla Ahmed Tinubu, gẹgẹ bii ẹni to jawe olubori, ki wọn si ṣeto idibo mi-in.

Yatọ si eyi, wọn tun ni oludije ẹgbẹ APC ti ajọ eleto idibo ilẹ wa ti fun ni iwe-ẹri ‘mo yege’ yii ko kun oju oṣuwọn lati dije dupo aarẹ ni asiko ti eto idibo naa n lọ lọwọ.

Nigba to n fidi rẹ mulẹ lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii, Adari ikọ ipolongo fun Obi-Datti, Dokita Yunsa Tanko, sọ pe loootọ ni pe awọn ti ko iwe ẹsun lori eto idibo aarẹ to kọja yii siwaju igbimọ olugbẹjọ idibo. O ni igbesẹ lati gba ẹtọ awọn araalu pada fun wọn ni igbesẹ rẹ bẹrẹ wẹrẹ yii.

Ajọ eleto idibo (INEC), Aṣiwaju Bọla Tinubu, igbakeji rẹ, Kashim Shetimma ati ẹgbẹ oṣelu APC ni wọn pe lẹjọ.

Tẹ o ba gbagbe, lẹyin idibo to kọja yii ni ajọ eleto idibo kede pe Aṣiwaju Bọla Tinubu lo bori ibo aarẹ to waye lọjọ kẹẹẹdọgbọn, oṣu Keji yii, ti oludije fẹgbẹ oṣelu PDP, Atiku Abubakar, lo wa ni ipo keji, nigba ti oludije funpo ẹgbẹ Labour, Petwer Obi wa ni ipo kẹta.

Ṣugbọn ni kete ti alaga ajọ eleto idibo, Mahmood Yaquub, kede pe Tinubu lo wọle ni Peter Obi ti jade pe oun ko gba esi idibo naa wọle. O ni igbesẹ ti eto idibo naa gba waye ko ba ofin mu, nitori gbogbo awọn igbesẹ ti ajọ eleto idibo ṣeleri pe awọn maa gbe lasiko eto idibo ni wọn ko gbe.

Leave a Reply