Jọkẹ Amọri
Temi ye mi ni ọkan ninu awọn oṣere ilẹ wa, Ẹbun Oloyede, ti gbogbo eeyan mọ si Ọlaiya Igwe fọrọ ṣe lori bi awọn kan ṣe n bu u pe o rin nihooho ọmọluabi lọ seti okun lati lọọ gbadura fun oludije funpo aarẹ lẹgbẹ oṣelu APC, Aṣiwaju Bọla Tinubu.
Oṣere naa ni oun ko fẹẹ ya alaimoore lo jẹ ki oun ṣe ohun ti oun ṣe yii. O ni ti ko ba si ti iyawo Aṣiwaju Tinubu, boya oun iba ti di ẹni akọlẹbo. Nigba ti oun dubulẹ aisan, obinrin yii ni Ọlọrun lo fun oun ti oun fi ri itọju. O ni koda, obinrin naa fẹẹ gba fisa foun lati lọ si ilu oyinbo fun itọju, nibi ti ọrọ oun jẹ ẹ logun de.
Ọlaiya ni, ‘‘Nigba kan ti ara mi ko ya gidigidi, iyawo Tinubu yii, Rẹmi, Rẹmi, Sẹnetọ Rẹmi, oun lo pe Ajala, Ajala Jalingo nigba yẹn ti mo siiki pe ki wọn maa gbe mi lọ sileewosan ijọba n’Ikẹja, lọdọ maanu yẹn, Nurudeen Olowopopo, o ti ku bayii, oun lo jẹ adari ọsibitu yii nigba yẹn.
‘‘O tun waa pe mi lọjọ kẹta pe ṣe mo ṣi ni fisa Amẹrika, ti mi o ba si ni ki wọn ṣeto fisa yẹn fun mi ki wọn tete maa gbe mi lọ si Amẹrika. O ni Ọlaiya ko gbọdọ ku. Ṣe ọkọ iru eeyan bẹẹ yẹn yoo waa jade pe oun fẹẹ dupo aarẹ, ma a waa jẹ ọmọ ale, ma a waa lọọ ṣatilẹyin fun ẹlomi-in…’’
O fi kun un pe ko si oludije to fakọ yọ to Tinubu ninu gbogbo awọn to fẹẹ dupo aarẹ.
Ọkunrin ọmọ bibi ilu Abẹlokuta yii kọ ọ sori ikanni Instagraamu rẹ pe, ‘‘O jẹ ohun idunnu fun mi lati ṣatilẹyin fun ẹni ti erongba rẹ ba daadaa ti awa naa n reti mu. Ẹni kan ṣoṣo naa lo le mu ala yii wa si imuṣẹ ninu awọn oludije yii lasiko idibo to n bọ.
‘‘Adari kan ṣoṣo ti yoo ja fita fita lati mu ileri Naijiria ṣẹ fun awọn iran to n bọ. Idi niyi ti gbogbo wa fi gbọdọ dide, ki a si yan AṢIWAJU BỌLA TINUBU JAGABAN gẹgẹ bii aarẹ wa ni ọdun to n bọ’’. Ẹbun Oloyede ti gbogbo eeyan mọ si Ọlaiya Igwe lo sọ bẹẹ.