Adewale Adeoye
Gbajumọ oṣere tiata nni, Ibrahim Chatta, ti sọ pe ki i ṣe tuntun rara pe keeyan ma gba ami-ẹyẹ gẹgẹ bi oun paapaa ko ṣe ti i gba a latigba toun ti n ṣe fiimu agbelewo ati sinima lorileede yii. Oṣere yii ni ohun kan ṣoṣo to n kọ oun lominu nibẹ ni bi awọn to n ṣeto awọọdu naa ki i ṣee fiwe pe oun nigba gbogbo ti wọn ba ti fẹẹ ṣeto naa lọdọọdun nilẹ wa, eyi to sọ pe ọrọ ọhun lọwọ kan abosi ninu ni.
Ibrahim Chatta sọrọ yii di mimọ lọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu Karun-un, ọdun 2023 yii, lori eto ‘Lagbo Oṣere’, nibi ti atọkun eto naa, Gbenga Ọlayiwọla, ti pe e lori foonu rẹ, ti Ibrahim Chatta si sọ ẹdun ọkan re fun atọkun naa. O ni inu oun ko dun rara si bawọn to n ṣeto ami-ẹyẹ AMVCA ki i ṣee fiwe pe oun nigba gbogbo ti wọn ba n ṣeto naa nilẹ wa. Ni pataki ju lọ, eyi to waye gbẹyin yii.
Ibrahim Chatta ni, ‘Ohun ti mo mọ daadaa ni pe fiimu kan ti mo ti kopa, eyi ti wọn pe ni ‘Ọba awọn ole’ (King Of Thieves), n ṣe daadaa laarin ilu. Eyi ni awọn to n ṣeto awọọdu ‘Africa Magic Viewers Choice Award’ (AMVCA), ro papọ ti wọn fi darukọ fiimu naa mọ awọn to gba ami-ẹyẹ lọdun yii, ṣugbọn ti wọn ko fiwee kankan pe mi lati wa sibi eto pataki naa. Mi o mọ idi ti eyi fi ri bẹẹ o, o si ti digba gbogbo to maa n waye, ẹnu tiẹ maa n ya mi nigba ti mo ba ri awọn oṣere tiata kọọkan to jẹ pe wọn ba mi lẹnu iṣẹ yii ni tawọn naa maa n lọ sibi eto naa lọdọọdun.
‘‘Bi wọn ki i ṣee pe mi sibi eto ami-ẹyẹ naa ko tu irun kankan lara mi rara, mi o si ni i jẹ ki eyi da mi lọkan ru. Mo mọ daadaa pe awọn ẹlẹgbẹ mi gbogbo nidii iṣẹ tiata naa n ṣiṣẹ takun-takun ninu iṣẹ wọn, onikaluku naa ni ami-ẹyẹ si tọ si, nidii eyi, mi o ri i ro rara lati gba awọodu ilẹ yii, awọọdu to ju tilẹ yii lọ, iyẹn ‘Oscar’, nilẹ Amerika lo wu mi lati gba bayii, lagbara Ọlọrun Ọba, ma a si ri i daju pe mo gba a ki n too fiṣẹ tiata yii silẹ’’.