Idowu Akinrẹmi, Ikire
Titi dasiko yii ni ọkunrin sọrọsọrọ kan, Ọlalekan Ayinde tawọn eeyan mọ si ‘Abẹrẹ ọrọ’, n’Ikire, ipinlẹ Ọṣun, ṣi n dupẹ f’Oluwa pẹlu bo ṣe bọ lọwọ awọn ajinigbe to wọ mọto wọn lọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu kẹsan-an, ọdun 2020.
Ibadan lọkunrin naa n lọ gẹgẹ bo ṣe ṣalaye f’AKEDE AGBAYE. O ni titi iwaju ile oun loun ti maa n wọ awọn mọto sọọlẹ ti wọn ba n lọ lati Ikire si Ibadan, ko si bu oun lọwọ ri, layọ loun maa n de ile Oluyọle lai si iyọnu, afi ti ọsẹ to kọja to jẹ pe diẹ lo ku koun ba irin-ajo naa rin.
Abẹrẹ ọrọ sọ pe, ‘Lọjọ Iṣẹgun to kọja yii, iwaju ita mi naa ni mo ti wọ mọto, nitori oroju ati lọ si gareeji yẹn maa n ṣe mi. Ohun ti mo kan ri ni pe bi mo ṣe da mọto duro ti mo beere pe eelo ni, wọn o da mi lohun, wọn ṣaa ni ki n wọle. Mo ri i pe obinrin kan bọ silẹ ninu mọto naa, eeyan meji wa niwaju, meji leyin, emi ni mo ṣikarun-un wọn, a ṣaa n lọ, wọn o sọ iye ti wọn fẹẹ gba, ni mo ba n ro o pe boya wọn fẹẹ gbe mi lọfẹẹ ni.
‘‘Ka too de ọdọ awọn ọlọpaa ni dẹrẹba ti n naka soke, ko duro nigba ta a de Ọlọpẹ meji ti awọn ọlọpaa ti da wa duro, diẹ lo ku kawọn iyẹn gan-an fibọn fọ gilaasi mọto wa, nibẹ lẹru ti bẹrẹ si i ba mi, mo mọ pe mo ti ṣi ọkọ wọ.
‘‘Ẹni to jokoo lẹgbẹẹ mi gba ipe kan, dẹrẹba naa gba ipe, bo ṣe fi foonu ẹ sibi to ti mu un pada bayii lo bẹrẹ si i rẹ mi, mo waa n sọ fun wọn pe mo fẹẹ bọ silẹ, mi o lọ mọ, wọn o dahun, wọn ti wainii gbogbo gilaasi ọkọ soke, wọn ti tilẹkun ọkọ pa, a dẹ ti fẹẹ wọ ibi ti igbo wa, mi o fẹẹ le sọrọ mọ, o ti rẹ mi gidi.
‘’Nigba ti mo ti ri nnkan to n ṣẹlẹ yẹn ni mo waa bẹrẹ si i gba gilaasi ẹgbẹ mi bii ko fọ, mo bẹrẹ si i pariwo ki wọn ma baa le ri mi gbe sa lọ. Obinrin to wa ninu wọn lo pada sọ pe ki wọn duro, ki wọn jẹ ki n sọkalẹ, wọn ṣaa duro fun mi, ṣugbọn niṣe ni wọn tun bẹrẹ si i fi mọto le mi latẹyin.
‘’Mo ri korope kan ti mo ni ko gbe mi, niṣe niyẹn tun fẹẹ lọọ sọ mi siwaju wọn. Nigba ti mo si pariwo tawọn eeyan ba mi le wọn, wọn o ba wọn mọ.’’
Ọkunrin yii sọ pe aanu Ọlọrun loun ri gba toun fi bọ lọwọ awọn ajinigbe, o si rọ awọn ero to ba fẹẹ wọ mọto pe ki wọn maa lọ si gareeji ti wọn ba fẹẹ wọkọ.
O ni ki wọn ma ro ti pe owo ibẹ maa n pọ, ẹmi wọn ni ki wọn ro, nitori awọn ajinigbe wa looọtọ, ẹni to ba n wọ sọọlẹ lo si rọrun fun wọn ju lati gbe sa lọ.