Ọlawale Ajao, Ibadan
‘Mo tun n lọ si awọn ipinlẹ yooku, awọn Fulani gbọdọ fi ilẹ Yoruba silẹ dandan ni’ Akikanju ọmọ Yoruba nni, Sunday Igboho lo ṣe ileri yii lẹyin to ti ilu Igangan, nipinlẹ Ọyọ, nibi to ti lọọ le awọn Fulani jade kuro.
Ko too di pe Igboho atawọn ẹmẹwa ẹ le awọn afurasi ọdaran Fulani kuro ni ipinlẹ Ọyọ lọkunrin naa ti ṣeleri pe oun n lọ si awọn ipinlẹ yooku naa nilẹ Yoruba. O si ti tun un sọ lẹyin to ti ṣe tipinlẹ Ọyọ laṣeyọri tan. O ni dandan, awọn Fulani gbọdọ fi ilẹ Yoruba silẹ, bẹẹ lo ni ki awọn Fulani darandaran naa maa reti oun ni awọn ipinlẹ ilẹ Yoruba to ku.