N ko fẹẹ sọrọ lori ohun ti Bọla ṣe fun Ọọni Ifẹ ti gbogbo wa ri ninu fidio. N ko fẹẹ wi nnkan kan, ko ma jẹ eyi ti n ba wi ni wọn yoo maa gbe kiri. Gbogbo iru eleyii la ti ri ri, a ti ri i daadaa nile yii. Ṣugbọn ko si eyi ti a ri to yọri si daadaa fun awọn to ṣe e: gbogbo awọn ti wọn maa n ta Yoruba, paapaa fun awọn Hausa, gbogbo awọn ọmọ wa ti wọn maa n kọ idi sita ti wọn yoo si maa tọ sinu ile, gbogbo awọn eeyan ti wọn maa n gbagbe orirun wọn nitori ọrọ oṣelu, ti wọn yoo si fa Yoruba sẹyin, ti wọn yoo le wọn jinna si oriire wọn, emi ko ri ẹni to ṣe bẹẹ to ṣe e gbe ninu wọn ri, wọn aa maa jiya rẹ titi dori awọn arọmọdọmọ wọn ni. Ọdalẹ ni wọn, iran ọdalẹ kan ki i lọ lai jiya nilẹ Yoruba, nitori ko si ijamba ti oloṣelu, tabi ẹni ti Ọlọrun gbe dide kan le ṣe fawọn eeyan ẹ ju ko ta wọn si oko ẹru lọ. Iru awọn Bọla ti wa daadaa ri, ti wọn n ta Yoruba soko ẹru, ṣugbọn igbẹyin wọn ko daa, a oo si ma wo ibi ti igbẹyin oun naa funra rẹ yoo ja si.
Nitori ẹ ni n o ṣe fẹẹ wi kinni kan: akerengbe ni yoo sọ ibi ti wọn yoo ti okun bọ, Ọlọrun kuku ṣe e, aye ti lu jara ju tatijọ lọ, gbogbo ohun ti awọn eeyan yii n ṣe lo wa ninu akọsilẹ, akọsilẹ ti ko ṣee parẹ, ọjọ n bọ ti wọn yoo wa ẹkun ti wọn ko ni i ri omi loju wọn. Tabi kin ni ti Yoruba ti ṣe ri bayii! To jẹ awọn eeyan tiwa, awọn ti wọn bi ni ilẹ Yoruba, ti wọn ṣiṣẹ ni ilẹ Yoruba, ti wọn ṣe oriire ni ilẹ Yoruba, to jẹ owo Yoruba ni wọn n na, iran Yoruba lo gbe wọn dide, to waa jẹ awọn naa ni wọn yoo sopanpa, ti wọn yoo ko awọn araata wa pe ki wọn waa ko Yoruba lẹru, ti wọn yoo sọ pe nitori agbara oṣelu ti awọn n wa ni. Bi wọn ba ri agbara oṣelu naa, kin ni wọn yoo fi ṣe lẹyin ti wọn ba ti ba ile ti wọn ti jade jẹ, ti wọn ti sọ awọn eeyan tiwọn dero ẹyin. Kin ni wọn le fi iru agbara oṣelu bẹẹ ṣe! Nibo ni wọn ti fẹẹ lo o!
Bakan naa, n o fẹẹ sọrọ lori ija to n lọ ninu ẹgbẹ awọn Yoruba World Congress, mo fẹ ki awọn ẹgbọn wa ti wọn n mura lati yanju ọrọ yii tubọ ṣe e debi kan, bi ọrọ naa ko ba waa ṣee yanju, to ba jẹ loootọ ni wọn yan awọn eeyan kan lati waa fọ ẹgbẹ naa, to jẹ awọn ti wọn n ja lati gba ipo olori ẹgbẹ yii ti wa ni Naijiria ati nilẹ Yoruba lati ọjọ aye wọn ti wọn o ri iru ẹgbẹ yii da silẹ ki Ọjọgbọn Banji Akintoye too de, ti awọn kan dide lati da ẹgbẹ naa silẹ, ti kinni naa si n lọ geere ko too di pe wọn yọ kumọ lati lu u fọ, ma a jade lati tu aṣiri awọn ohun to ṣẹlẹ gan-an, nigba naa la maa mọ ẹni to ba yẹ ki Yoruba juko fun, awọn to yẹ ki Yoruba jinna si, ninu awọn agba agbẹyinbẹbọjẹ to kun aarin wa. Akintoye le ni iwa tirẹ lọwọ, Ṣugbọn afi ka le akata jinna ka too ba adiẹ wi ni. Ọrọ naa n gbe mi ninu, ṣugbọn ma a ṣe suuru diẹ.
Ohun to kan mi loni-in yii, ti mo si fi pa gbogbo ọrọ ti mo n ba bọ lati ẹyin tẹlẹ ti ni ki n pe Ọlọrun Yooba, ki n pe gbogbo awọn alalẹ Yoruba, ki n pe gbogbo awọn oludasilẹ Yoruba, pe nibi yoowu ti wọn ba wa ki wọn dide. Bi Ọlọrun ko ba dide si ọrọ wa, ti awọn alalẹ ile Yoruba ko ba dide, ohun ti yoo ṣẹlẹ si Yoruba, iyẹn awọn Yoruba to wa ni Naijiria yii, ohun to ṣẹlẹ si wa nilẹ wa yii, kinni ni naa ko ni i ṣee fẹnu sọ o. Awọn Fulani ti yi wa ka o, wọn yi wa ka patapata, wọn yi wa po debii pe bi kinni kan ba ṣẹlẹ loni-in yii, wọn yoo maa mu wa bii adiẹ ni, tọmọ-tọmọ, tọkọ-tọkọ, tiyawo-tiyawo, ti a ko si ni i ri nnkan kan ṣe si i. Ki Ọlọrun to ni ọjọ oni ma jẹ ki eleyii ṣẹlẹ si iran ati ẹya wa, ko ma ṣẹlẹ nile ẹni kọọkan wa. Ṣugbọn ohun ti mo n ri, iran ti mo n ri, bi ọrọ ti n lọ ni Naijiria, kinni naa le ṣẹlẹ, ni mo ṣe mu un wa si etiigbọ yin, boya nnkan kan wa ti a ṣi le ṣe.
Boya ẹ ko gbọ iroyin kan to ja ran-in ran-in lọsẹ to kọja, ọkunrin kan lo gbe ọkada kan ni Lẹkki, loju ẹ bayii lọmọ ọlọkada Hausa yii ṣe fa ẹwu kan yọ, lo ba wọ ọ, wọn kọ Gallant Vigilante si i lara. Hausa ni o, ki i ṣe Yoruba o. Bẹẹ ni wọn tun pade ekeji ẹ lọna, iyẹn naa ni iru aṣọ kan naa, aṣe wọn n lọ si ipade ni. Nigba ti ọkunrin yii bọ silẹ, o gbe ọlọkada mi-in, o ni ko tẹle wọn. Wọn de ile akọku kan laduugbo naa, nibẹ ni bii aadọta awọn ọmọ Hausa ati Fulani ti wọn wọ iru aṣọ yii wa, ti wọn n ṣepade. Awọn mi-in ni ọbẹ alaṣooro lọwọ, awọn mi-in ni ida ti wọn tọju pamọ, awọn mi-in ni ibọn ilewọ lara ọkada wọn. Wọn ti da aṣọ fijilante funra wọn, bi eeyan ba pade wọn loru, yoo ro pe fijilante gidi loun pade, bi wọn ṣe maa digun ja tọhun lole niyen. Fijilante Fulani nilẹ Yoruba, ko si orukọ wọn ninu iwe kan, ṣebi ole ati janduku ni wọn maa ṣe gbẹyin, awọn ni wọn si n fi ọkada gbe awọn eeyan wa kiri yii o.
Nigba ti awọn ọlopaa ri fọto ti ọkunrin to ri wọn yii ya lori ẹrọ ayelujara, wọn bẹrẹ si i sare kiri, wọn ni wọn n wa awọn ọmọ ẹgbẹ fijilante Fulani yii kiri. Nibo ni wọn wa tẹlẹ, nibo ni awọn ọtẹlẹmuyẹ wọn wa, nibo ni awọn DSS ti wọn maa n kiri ile oloṣelu wa, bawo ni Fulani ati awọn Hausa yoo ṣe da fijilante silẹ nilẹ Yoruba ti ko ni i si ẹni to ri wọn ninu awọn agbofinro ijọba. Awọn Fulani ti pọ nilẹ Yoruba bayii debii pe ko si ara ti wọn ki i da. Ọsẹ to kọja la ka iroyin pe Fulani onimaaluu lọọ digun jale nile onile ni Ewekoro, nitosi Abẹokuta, wọn mu ọmọ iya ti wọn ka mọle loru yii lọ sinu oko paki, awọn Fulani mẹtẹẹta si fi tipa ba a sun ninu oko nibẹ. Ki i ṣe pe wọn o mọ awọn Fulani yii o, wọn mọ wọn daadaa, wọn ni wọn maa n da maaluu kọja laduugbo wọn lọsan-an, ṣugbọn ti wọn ba da maaluu lọsan-an, to ba di alẹ, wọn aa di adigunjale. Nilẹ Yoruba tiwa nibi yii naa si ni.
Awọn mi-in a tiẹ maa bi mi pe ki lo de, tabi pe bawo lawọn Fulani ati Hausa ṣe waa pọ nilẹ Yoruba bayii, ati pe kin ni wọn n wa. Kinni naa ti bẹrẹ lati bii ọdun mẹwaa sẹyin, ṣugbon nigba ti Buhari gbajọba yii, kinni naa waa le si i ni bii ilọpo ọgọrun-un, lojoojumo ni. Lọjọ kan, a n lọ lati Ibadan si Eko, eleyii ko ti i pẹ rara o. Laarin wakati meji aabọ ti a fi rin irin naa, mo ka terela to n bọ l’Ekoo lati ilẹ Hausa bii mejilelogun. Ninu terela kọọkan, eeyan bii ogoji si aadọta le wa nibẹ, koda ki wọn ko ẹran si i, wọn aa jọ wa nibẹ ni. Mo wo titi, o su mi, mo ti ri bii meji mẹta ki n too sọrọ pe iru ewo leleyii, ṣe gbogbo terela to ba n bọ lati ilẹ Hausa lo n ko ero bayii ni. Awọn ti a jọ n lọ fi ẹsẹ ẹ mulẹ pe bẹẹ ni, pe lojoojumọ, bi wọn ti nko wọn wa ree, awọn gende, awọn igiripa ọkunrin, awọn ọdọ ti wọn leegun lara daadaa.
Gbogbo awọn agbaagba ti mo le ba sọrọ ni mo pe, nitori ni orilẹ-ede yoowu, tabi ilu yoowu ti awọn igiripa ọkunrin elede mi-in ba n rọ wọ bi wọn ṣe n rọ wọ Eko yii, ogun yoo ṣẹlẹ nibẹ gbẹyin ni. Ati Boko Haram, ati awọn afẹmiṣofo, gbogbo wọn lo ti rọ wọle wa, ati Fulani ati awọn apaayan loriṣiiriṣii. Ni bayii, wọn ti ni ẹgbẹ, wọn ti ni ọmọ ogun. Laarin wa yii naa ni o, wọn si ti wa niṣọkan lati ṣe ohun yoowu ti wọn ba fẹẹ ṣe. Ko si ohun meji ti wọn wa wa ju owo ati ọrọ̀ ilẹ Yoruba lọ, ohun-ini ati awọn ohun ti a fi n ṣe ọrọ̀ ni wọn wa wa, ohun to si wu wọn ni ki wọn gba ilẹ ati awọn ohun ta a ni yii lọwo wa, ki wọn di olori le wa lori ni tipatipa. Ko si bi wọn ṣe fẹẹ di olori le wa lori ti ko ni i jẹ ogun ni wọn maa ba wa ja, ogun naa yoo si buru, nitori wọn yoo pa awọn eeyan bii ẹran ni, nitori awa ko mura silẹ. Lọjọ ti ọrọ kekere ba ṣẹlẹ ni wọn aa sọ ọ di ogun mọ wa lọwọ, bẹẹ lawọn aṣaaju kan wa nibi kan ti wọn n kọ wọn lohun ti wọn maa ṣe fun wa.
Ṣugbọn gbogbo eleyii ko ni i jẹ nnkan kan bi ko jẹ awọn ọmọ tiwa ti wọn wa nijọba, ati awọn oloṣelu bii Bọla, awọn yii gan-an ni ọta ile ti Yoruba ni, awọn ni wọn fẹẹ fi wa fun awọn ọta ode mu. Bi eleyii ṣe ri bẹẹ, n oo maa ṣalaye fun yin ̀lọsẹ to n bọ. Ṣugbọn ẹ ma sinmi o! Ẹyin naa ẹ maa gbadura si Ọlọrun Yoruba, Ọlọrun gbogbo aye, ko ko iran Yoruba yọ lọwọ dugbẹ dugbẹ to n mi lori wa yii, nitori bi kinni naa ba ja bọ, ọkan ninu awọn ogun ati ipaniyan ti yoo buru ju lọ lagbaaye ni. Ki Ọlọrun ma je ka ri i o.
Olohun a kuku bawa se.