Kin ni idi ti mo ṣe sọ pe awọn oloṣelu ti wọn jẹ ọmọ Yoruba tiwa nibi ni wọn n ko ba wa. Mo sọ pe awọn ni agbẹyinbẹbọjẹ, awọn ni wọn n gbabọde fun ilẹ Yoruba, awọn oloṣelu ti wọn jẹ ọmọ tiwa ni wọn ko jẹ ki nnkan lọ bo ti yẹ ko lọ fun wa. Ki lo de ti mo fi sọ bẹẹ? Ẹ wo o, mo fẹẹ ṣe awọn alaye kan fun yin lori ohun to n ṣẹlẹ ni Naijiria yii, ki itumọ ọrọ ti mo n sọ bọ lati ọsẹ to kọja le ye yin. Mo fẹ ki ẹ kọkọ mọ kinni kan, iyẹn ni pe ki i ṣe orilẹ-ede Naijiria nikan lawọn Fulani wa o: wọn wa ni Ghana, wọn wa ni Togo, wọn wa ni Abidjan atawọn orilẹ-ede mi-in, iyatọ to kan wa nibẹ ni pe ko sibi ti aaye igbakugba ti gba wọn bii ti Naijiria yii ni. Bẹyin naa ba ranti daadaa, aaye buruku bayii ko gba Fulani nilẹ wa tẹlẹ, ṣebi awọn Fulani yii ti wa laarin wa lọjọ to ti pẹ, asiko ijọba Buhari yii ni wọn jẹwọ pe awọn ki i ṣeeyan daadaa ni.
Nigba ti ọwọ wọn ko ba ti i ba eeku ida, iyẹn ti ki i ṣe ẹya tabi iran wọn lo n ṣejọba, jẹẹjẹ ni wọn yoo maa lọ. Tabi ẹyin ki i ri awọn Fulani onimaaluu ninu oko abule gbogbo to yi ilẹ Yoruba ka tẹlẹ ni! Fulani atijọ ki i paayan, koda wọn ki i jẹ ki maaluu wọn wọ inu oko oloko, jẹẹjẹ ni wọn n gbe ni gbogbo agbegbe ti wọn ba wa, ti eeyan ko si ni i mọ pe alejo kan tilẹ wa laarin wọn. Bẹẹ ni wọn aa maa da maaluu wọn, ti awọn iyawo wọn aa si maa ṣe wara fun gbogbo awọn ara agbegbe naa jẹ. Ko ju bẹẹ lọ. Ṣugbọn awọn ti wọn n da maaluu kiri yii gangan kọ ni Fulani oniwahala, awọn olori wọn, awọn aṣaaju wọn, awọn eeyan bii Muhammadu Buhari tiwa nibi, ati awọn mi-in lati inu iran wọn, ti wọn ti wa sigboro, ti wọn ti laju, ti wọn si ti tọ agbara oṣelu wo, awọn ni wọn bẹrẹ si i ran awọn Fulani inu igbẹ wọnyi niṣẹ, ti wọn n ha ohun ija oloro fun wọn.
Ohun ti wọn ṣe n ṣe eleyii ni pe ni orilẹ aye yii, ko si ibomi-in ti aaye ti gba wọn bayii, nitori wọn ko da ni orilẹ-ede tiwọn, alarinkiri ni wọn. Ohun to wa lọkan wọn bayii ni lati fi Naijiria ṣe ile wọn, nibi ti wọn yoo maa pe ni orirun awọn Fulani. Wọn ko le pe Naijiria ni ile wọn, tabi pe awọn lawọn ni in bi Yoruba ba wa nibẹ, bi Ibo ba wa nibẹ, bi awọn Tiv ati awọn Ijọ naa ba wa nibẹ, eleyii yoo ṣoro fun wọn. Ohun ti wọn ṣe n lo gbogbo agbara ofin yoowu to ba ti de ọwọ wọn, tabi ti wọn ba ni, lati fi awọn Fulani ara wọn, tabi awọn Hausa to gbọran si wọn lẹnu, si ipo olori ileeṣẹ ijọba gbogbo pata, bo jẹ toloogun, bo jẹ ti awọn iṣẹ ọba to ku, debii pe bi ẹ yi sọtun-un, Fulani ni yoo maa paṣẹ, bi ẹ yi si osi, Fulani ni yoo maa paṣẹ, nigbẹyin, ko si kinni kan ti ẹ oo le da ṣe lai ri Fulani, tabi ki wọn fọwọ si i.
Ṣe eleyii ko ti waa n ṣẹlẹ ni Naijiria yii ni! Ẹyin naa ẹ wo ayika yin, ko si iṣẹ ti awọn eeyan wa le ṣe, ti wọn ko ba fi Fulani si i, tabi ki wọn fi Hausa si i, ijọba apapọ ko ni i fi ọwọ si i. Bi wọn jẹ kọntirakitọ, afi ti wọn ba fi ọmọ Hausa kan si aarin wọn, ohun ti wọn fi le maa ri iṣẹ gba lọwọ ijọba apapọ niyi. Ọmọ Hausa tabi Fulani yii ko ni iṣẹ kan to n ṣe fun wọn ju pe ki wọn ṣaa fi orukọ ẹ si i ko si maa gbowo, ki awọn eeyan ẹ to wa nile ijọba si mọ pe oun naa ni ipin ninu ileeṣẹ naa, ohun ti wọn fi le ri owo tabi iṣẹ gba lọwọ ijọba apapọ niyẹn. Bi bẹẹ kọ, ki wọn kọ iwe ogun, ki wọn kọ iwe ọgbọn, ko sẹni kan to maa sọ pe oun ri i. Gbogbo ileeṣẹ elepo, gbogbo ileeṣẹ to n ṣe titi, gbogbo ileeṣẹ to n ba wọn kọle, gbogbo ileeṣẹ to n ba wọn ṣiro owo, bi ẹni kan ba da iru ileeṣẹ bẹẹ silẹ ti ko sọmọ Hausa ninu awọn ọga to ni in, wọn aa ti i pa gbẹyin ni, afi ti o ba fẹ kinni kan lọwọ ijọba apapọ lo ku.
Ọpọlọpọ awọn ọmọ wa lorilẹ-ede yii, nilẹ baba wọn, ni wọn wa ninu iṣẹ ologun, to jẹ orukọ wọn kọ ni wọn lo, orukọ Hausa ni wọn lo ki wọn le mu wọn. Bẹẹ Yoruba tabi Ibo ni wọn. Bakan naa lo jẹ ọpọ awọn ọmọ wa ni wọn wa ni yunifasiti nilẹ Hausa, ti wọn n lo orukọ Hausa, tabi ti wọn ni ibẹ lawọn n gbe, nitori bi wọn ko ṣe bẹẹ, wọn ko ni i ri yunifasiti wọ. Nigba ti iru awọn nnkan wọnyi ti wa lọwọ wọn ni aya ṣe kò wọn lati jẹ ki awọn Fulani ati Hausa maa rọ wọ ilẹ Yoruba ati ilẹ Ibo lojoojumọ, ti ko si sẹni to le da wọn pada. Ibẹru temi ni pe bi nnkan ti n lọ yii, nigba ti yoo ba to ogun si ọgbọn ọdun si asiko ti a wa yii, boya lawọn ọmọ Hausa ti yoo wa nilẹ Yoruba ko ni i pọ ju awọn ti wọn jẹ ọmọ Yoruba gan-an lọ. Iru eleyii ki i bi ọmọ rere, ogun ni yoo da silẹ lọjọ iwaju, ibẹru mi si tun ni pe bi ogun ba ṣẹlẹ, nitori pe wọn yoo ti pọ ju awọn ọmọ tiwa lo, o ṣee ṣe ki wọn ṣẹgun wa.
Bawọn Fulani ba jagun nilẹ Yoruba ti wọn ṣẹgun, ko si ohun ti yoo ṣẹlẹ ju ki wọn mu ori awọn ọmọ oniluu mabẹ lọ, iru ohun to n ṣẹlẹ ni ilu Ilọrin lati ọdun yii waa yoo si maa ṣẹlẹ, Fulani yoo si maa jọba, wọn yoo maa paṣẹ oṣelu, awọn ọmọ wa, tabi awa paapaa ti a ba wa laye, a ko si ni i ri kinni kan ṣe si i. Awọn mi-in yoo maa leri bayii pe bi kinni naa yoo ba ṣẹlẹ, ko le ṣoju awọn, awọn yoo ti lọ. Iyalẹnu ni yoo jẹ pe ẹlomi-in ko ni ti i lọ sibi kan ninu wọn, nitori ọjọ iku rẹ ko ti i pe, yoo wa nibẹ, yoo si jẹ kinni kan, iya ni yoo jẹ, nitori asiko naa yoo buru fun awọn arugbo gan-an ni. N ko sọ gbogbo eleyii lati daya ja yin, tabi lati ko ilu lọkan soke lasan, ṣugbọn mo n sọ ọ nitori apẹẹrẹ to maa n ṣaaju ki iru awọn ohun wọnyi too ṣẹlẹ, gbogbo ẹ lo n ṣẹlẹ ni Naijiria lọwọlọwọ bayii, bẹẹ awọn apẹẹrẹ naa ki i ṣe apẹẹrẹ daadaa.
Apẹẹrẹ ibẹrẹ ogun ni. Ogun ti yoo le ni. Nibi ti irẹjẹ ba ti gbilẹ to bi awọn Fulani wọnyi ṣe n rẹ wa jẹ ni Naijiria, ti wọn n rẹ Yoruba jẹ, ti wọn n rẹ Ibo jẹ, ti wọn n rẹ Ijọ jẹ, ti wọn si n fi han wa pe awọn n rẹ wa jẹ, ko si kọrọ naa ma dogun, ogun gbigbona paapaa. Nitori ẹ ni mo ṣe n sọ gbogbo ohun ti mo n sọ, ki i ṣe lati daya ja yin. Mo fẹ ki ẹ mọ pe ki i ṣe Naijiria nikan ni wọn ti ni oriṣiiriṣii ẹya ni orilẹ-ede wọn. Awọn ẹya nla mẹrin, tabi orilẹ-ede mẹrin, lo wa ni United Kingdom ti a n gbọ okiki wọn yii, iyẹn niluu awọn oyinbo to mu wa sin nijọsi, lọdọ awọn ti a ti gba ominira wa. Awọn naa ki i ṣe elede kan, tabi orilẹ-ede ẹya kan ṣoṣo. Awọn English wa nibẹ, awon ni wọn fi England ṣe orilẹ-ede, ti London si jẹ olu ilu fun wọn. Awọn Irish wa nibẹ ti wọn n fi Northern Ireland ṣe orilẹ ede, ti Belfast si jẹ olu ilu wọn.
Bakan naa ni awọn Scottish wa nibẹ ti wọn fi Scotland ṣe orilẹ -ede, ti Edinburgh si jẹ olu ilu wọn. Awọn Welsh ti wọn fi Wales ṣe orilẹ-ede naa wa nibẹ, awọn ni wọn fi Cardif ṣe olu ilu wọn. Ohun ti mo n sọ fun yin ni pe bi ẹ ba gbọ ti wọn ni United Kingdom, tabi Britain, awọn orilẹ-ede mẹrin, tabi awọn ẹya nla nla mẹrin (English, Weslh, Scottish ati Irish) ni wọn parapọ ti wọn n jẹ bẹẹ. Ede wọn ko jọra, bẹẹ ni aṣa ati iṣe wọn paapaa fi diẹdiẹ yatọ si ara wọn. Ṣugbọn awọn ni Britian ti wọn ko gbogbo aye lẹru fun igba pipẹ. Kin ni ko waa jẹ ki ilẹ tiwọn tuka lati bii irinwo ọdun ṣẹyin ti wọn ti wa? Ofin ti wọn la silẹ lati maa fi ṣe orilẹ-ede nla yii, ati awọn oloṣelu ibẹ ni. Awọn oloṣelu ẹya kọọkan ni wọn n ja fun ẹya kọọkan, ti wọn yoo si ja fun orilẹ-ede naa lapapọ. Ohun ti ilẹ Yoruba ko ni ree, awa ko ni oloṣelu to n ja fun ẹya tiwa, awọn oloṣelu “jẹun-soke”, “jẹun sapo” la ni, ohun to fẹẹ ko ba wa ni Naijiria niyẹn.
Ma a tẹ siwaju ninu alaye yii lọsẹ to n bọ, nitori ọrọ wa, paapaa awa Yoruba, n fẹ apero gidgididi.
Won ti ko baa Iran Yoruba pata
Olohun a saanu awa Yoruba, Oselu jeun sapo ni awon Asiwaju wa mo looto.