Ẹyin tẹ ẹ ba fẹẹ kopa ninu idije ibalopọ pẹlu ẹbun nla, ẹ maa bọ o

Monisọla Saka

Gbogbo ẹyin ọmọ Naijiria tẹ ẹ ba mọ pe ẹ da ara yin loju bo ba di ka sere ibalopọ, anfaani ti wa fun yín bayii lati ṣere naa. Yatọ si pe ẹ maa gbadun ara yin daadaa, ẹbun pataki tun wa fun ẹni to ba gbegba oroke, iyẹn ẹni to ba mọ ba a ṣe e tẹ abo lọrun daadaa.

Ijọba orilleede Sweden lo gbé ètò yii kalẹ o. Wọn ni ere idaraya ni ibalopo jẹ, ko si yatọ si awọn ere idaraya yooku. Eyi lo fa a ti wọn fi ni awọn yoo ṣeto ere ije onibaalopọ, ti yoo jẹ akọkọ iru ẹ lagbaaye.

Ere idaraya onitagbangba ti wọn fẹ kawọn eeyan fi ṣe ifigagbaga yii ni wọn ni awọn adajọ ere idaraya yoo wa nikalẹ lati mu ẹni to ba gbegba oroke, bẹẹ lawọn ero iworan to wa nibẹ naa yoo ri oriṣiiriṣii ara ti awọn akopa ti wọn yoo wa lẹnu ẹ fun bii wakati mẹfa lojumọ n da.

Ere ije onibaalopọ ti yoo bẹrẹ lọjọ kẹjọ, oṣu Kẹfa, ọdun yii, ni wọn pe ni ‘ldije onibaalopọ ilẹ Yúróòpù’ (European Sex Championship), yoo si gba wọn ni odidi ọsẹ mẹfa gbako, tawọn akopa ti wọn ti ṣeto akoko tonikaluku yoo jọ ta kangbọn yoo si wa lẹnu ẹ laarin iṣẹju marundinlaaadọta si wakati kan lojoojumọ

Lara awọn nnkan ti wọn yoo wo lati yan ẹni to ṣe daadaa ju lọ ni ibaṣepọ to lọọrin laarin ọkunrin ati obinrin naa, imọ nipa ibalopọ, ati bi wọn ṣe ni amumọra to.

Gẹgẹ bi Ileeṣẹ iroyin ilu naa ṣe sọ, ipele mẹta ni ere ije naa pin si, ki akopa kọọkan too le yege lati bọ si ipele to kan, o gbọdọ ni iye to gba ninu eyi to kọkọ ṣe na.

O kere tan, wọn gbọdọ ni maaki marun-un si mẹwaa, lẹyin tawọn igbimọ adajọ ẹlẹni marun-un, atawọn ero iworan ba dibo fun wọn tan nipasẹ ariwoye wọn.

Oriṣiiriṣii ara ti wọn ba da ati nnkan to ba jẹ ki tiwọn yatọ si tawọn yooku lawọn ero iworan yoo wo, ti wọn yoo fi dibo fẹni to ba ṣe daadaa ju lọ.

Dragan Bratych, ti i ṣe olori ajọ idije ere idaraya onibaalopọ lorilẹ-ede Sweden, ni ibalopọ ṣe pataki, nitori anfaani to n ṣe fun ara ati ọpọlọ.

“Gẹgẹ bii awọn ere idaraya yooku, ọna lati ri nnkan teeyan n fẹ ninu ibalopọ wa lori bi eeyan ba ṣe gbaradi si. Fun idi eyi, a o ri i daju pe ere idaraya yii tẹsiwaju.

Nnkan to tun mu ki ere yii yatọ sawọn to ku ni pe ọna lati mu inu ẹni keji dun lo da le lori.

“Kẹnikẹni too le pegede tabi jawe olubori ninu ere yii, onitọhun ni lati tẹ ẹni keji rẹ lọrun daadaa”.

Bratych waa ni igbagbọ oun ni pe ọjọ kan n bọ ti gbogbo agbanla aye yoo gba ibalopọ gẹgẹ bii ere idaraya ni tootọ.

Leave a Reply