Ẹyin tẹ ẹ n doju ija kọ Fulani nipinlẹ Ogun gbọdọ dẹkun ẹ-Ọlọpaa

 Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

Kọmandi ọlọpaa nipinlẹ Ogun ti kilọ fawọn eeyan to n doju ija kọ awọn Fulani nipinlẹ naa, pe ki wọn yee ṣe bẹẹ, paapaa, lapa ilẹ Yewa.

Ọjọ Ẹti, ọjọ karun-un, oṣu keji, ọdun 2021 yii, ni ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun fi ikilọ yii sode lati ọwọ Alukoro wọn, DSP Abimbọla Oyeyẹmi.

Wọn ni nnkan ibanujẹ lo jẹ pe gaa awọn Fulani to ti wa lawọn ilu yii tipẹ lawọn eeyan kan lọọ n doju ija kọ laarin ọjọ meloo kan si asiko yii, ti wọn n ko ogun ja wọn.

Atẹjade naa fi kun un pe o ti le logun ọdun tawọn Fulani yii ti wa nipinlẹ Ogun, wọn bi awọn mi-in silẹ Yoruba nibi ni, to jẹ wọn gbọ Yoruba, wọn si tun n powe, beeyan ba si pe wọn ni Yoruba, tọhun ko jayo pa.

Lati waa maa ba iru awọn eeyan bẹẹ ja, ka ni wọn ko gbọdọ da maaluu wọn tabi ka ni wọn ko le gbe lapa ọdọ wa lodi sofin ijọba gẹgẹ bi wọn ṣe wi.

Atẹjade yii waa fi kun un pe ṣugbọn awọn Fulani naa gbọdọ ri i pe awọn ko ba oko oloko jẹ, eyi to jẹ idi pataki tawọn eeyan ilẹ Yoruba ko fi fẹ awọn eeyan yii lọdọ wọn. Wọn ni ojuṣe awọn agbẹ Yoruba ati Fulani ni, lati fẹjọ awọn ọbayejẹ to n ti ilẹ ibomi-in wa lati da wahala silẹ han, ki wọn fa wọn le ijọba lọwọ.

Ninu ipade alaafia ti awọn alẹnulọrọ lori wahala to n ṣẹlẹ yii ṣe laafin Alaye ti Ayetoro, lọjọ kẹrin, oṣu keji yii, ni wọn ti bu ẹnu atẹ lu awọn iwa fifi maaluu jẹko oloko, biba iyawo oniyawo lo pọ atawọn iwa buruku mi-in ti wọn ni awọn Fulani maa n hu.  Wọn fẹnuko pe ẹni tọwọ ba tẹ to n ṣe iru eyi yoo jiya bo ṣe tọ labẹ ofin.

Bakan naa ni Alukoro sọ pe ọwọ ileeṣẹ ọlọpaa ti tẹ awọn ọbayejẹ kan lori ikọlu to ṣẹlẹ laipẹ yii, wọn ni awọn yoo fimu wọn danrin ki wọn le jẹ ẹkọ fawọn mi-in bii iru wọn.

Ipinlẹ alaafia nipinlẹ Ogun, bi ẹnikẹni ba si fẹẹ da omi alaafia naa ru, tọhun yoo jẹ iyan rẹ niṣu lawọn ọlọpaa wi.

Leave a Reply