Faaji ni mo fi ẹgbẹrun lọna ogun naira ti mo ta ori afẹsọna mi ṣe, mo si ju iyooku ara ẹ sodo – Taju

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Ọmọkunrin ẹni ọgbọn ọdun kan, Tajudeen Monsuru, ti sọ lagọọ ọlọpaa niluu Oṣogbo pe laaarin oṣu kan sira wọn loun pa awọn eeyan meji, ti oun si ta ori wọn ni ẹgbẹrun lọna ogun naira.

Lara awọn ti Taju ni oun pa ni afẹsọna rẹ, Alani Mutiyat, o ni oṣu mẹrin pere lawọn fi ṣọrẹ ko too di pe oun ati ọrẹ oun kan pinnu lati pa a nigba ti ẹnikan waa ba oun pe oun nilo ẹya ara eeyan fun oogun owo.

Ṣaaju ni kọmisanna ọlọpaa l’Ọṣun, Wale Ọlọkọde, ti ṣafihan Taju atawọn abaniṣiṣẹ rẹ; Garuba Lukman Famous, Hamsat Akeem ati Awayewaṣere Yusuf.

Ọlọkọde ṣalaye pe lọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu kọkanla, ọdun to kọja, ni awọn mọlẹbi kan niluu Iwo lọọ fi to awọn ọlọpaa leti pe ẹnikan dawati niluu naa, kia ni wọn si taari ọrọ naa si ẹka ọtẹlẹmuyẹ niluu Oṣogbo.

Lasiko iwadii ni ọwọ tẹ awọn afurasi mẹrẹẹrin yii, ti wọn si jẹwọ pe loootọ lawọn pa Akanbi Adeolu, Alani Mutiyat ati Akinloye Ibrahim.

Bakan naa ni Awayewaṣere jẹwọ ni tiẹ pe oun loun maa n ra awọn ẹya-ara ẹni ti wọn ba ti pa lọwọ wọn.

Nigba ti Taju n ba ALAROYE sọrọ, o ni ṣe loun jogun ba iṣẹ iṣegun, ati pe ọmọ bibi ilu Iwo loun. O ni oun niyawo, bo tilẹ jẹ pe o ti lọ, oun si bimọ meji ti wọn n gbe lọdọ iyawo oun.

O ni nigba ti Awayewaṣere sọ pe oun nilo ori eeyan loun pinnu lati lo Mutiyat to jẹ afẹsọna oun to waa ki oun nile lọjọ naa, nigba to si sun loun ati ọrẹ oun fun un lọrun pa.

Taju sọ siwaju pe lẹyin to ku tan lawọn ge ori rẹ, tawọn si lọọ ju ara to ku sinu odo. O ni ẹgbẹrun lọna ogun naira lawọn ta ori Mutiyat, faaji lasan lawọn si fi owo naa ṣe.

Ni ti Awayewaṣere, o ni oogun owo loun fẹẹ fi ẹya-ara eeyan toun ra lọwọ awọn Taju ṣe.

Ọlọkọde ti waa ṣeleri pe laipẹ ni gbogbo wọn yoo foju bale-ẹjọ.

Leave a Reply