Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta
Ni nnkan bii ọdun meji sẹyin niroyin gba igboro kan pe Ọgbẹni Ojo Arowoṣafẹ tawọn eeyan mọ si Fadeyi oloro ti ku. Bẹẹ, ọkunrin naa ko ku, aarẹ nla to gbe e dalẹ nigba yẹn lo jẹ ki okiki iku ẹ gba igboro kan.
Eeyan yoo ṣebi ohun gbogbo ti pada sipo fun Fadeyi ni, paapaa nigba ti awọn eeyan dide iranlọwọ fun un nigba naa, toun naa si ni ẹni to ba ro iku ro oun yoo wulẹ ṣaaju oun lọ sọrun ni. Ṣugbọn ni bayii, iṣoro ẹsẹ lọkunrin naa tun ko si, niṣe lẹsẹ osi rẹ ko ṣee wo, to jọ pe o n jẹra lọ.
Fadeyi ba ALAROYE sọrọ nirọlẹ ọjọ Abamẹta, Satide yii, ohun to sọ ni pe oun ko le rin lai lo igi, nitori ẹsẹ osi oun naa n mu inira ba oun gidi.
Lori ohun to tun fa iṣoro ẹsẹ, oṣere tiata yii sọ pe gbogbo ẹnu ko ṣee maa fi sọrọ, o ni ṣugbọn ọfa ni wọn sọ pe wọn ta oun lẹsẹ naa to fi bẹrẹ si i ṣaapaa, ti ko si wu oju i ri rara mọ.
O fi kun un pe ọsẹ kẹta ree toun ti ko si iṣoro ẹsẹ yii, kaakiri loun si ti n gba itọju rẹ, ki i ṣe ọna kan rara. Koda, ọkan ninu awọn ibi toun ti n gba itọju naa loun n lọ lasiko to ba wa sọrọ naa.
Ṣa, Fadeyi ni ara n ni oun pupo, ki gbogbo ọmọ Naijiria ṣaanu oun. Gẹgẹ bo ṣe wi, ‘‘Ẹ ma jẹ ki n ku tan kẹ ẹ waa maa sọ sọri fun mi, ẹ jọọ, ẹ ṣaanu mi. Ẹ ran mi lọwọ nipa owo ki n le tọju ẹsẹ mi yii. Ara mi le, ẹsẹ ni iṣoro ti mo tun ko si bayii’’