Jide Alabi
Gẹgẹ bi ọkan lara awọn ọmọ Ile-Ifẹ, Oloye Fẹmi Fani-Kayọde, ti sọ pe ko si ọba kan to ti jẹ ri n’Ifẹ tabi to wa lori itẹ to jẹ ẹru Fulani ri, bẹẹ lo sọ pe Sunday Igboho ti bẹbẹ lori bo ṣe pe Ọba Adeyẹye Ogunwusi ni ẹru Fulani.
Fani Kayọde sọ pe oun ti pe ọkunrin ajijagbara iran Yoruba naa, bẹẹ lo ti sọ pe inu lo n bi oun lasiko ti oun sọrọ ọhun toun fi sọ pe iwa Ọọni Ile-ifẹ niwaju Muhammadu Buhari, bii ẹni to ti dẹru awọn Fulani ni.
Ọkunrin naa sọ lori ikanni agbọrọkaye rẹ pe, “Mo ti pe Sunday Adeyẹmọ, ẹni ti gbogbo eeyan tun mọ si Igboho, o si ti fi da mi loju pe ki i ṣe pe oun mọ-ọn-mọ pe Ọọni ni ẹru Fulani, inu lo bi oun lasiko ti oun sọrọ naa.
“Ninu ọrọ ta a jọ sọ, o jẹ ki n mọ pe oun kabaamọ ọrọ ti oun sọ yẹn, bẹẹ lọkan temi naa walẹ lẹsẹkẹsẹ. Eyi gan-an ni mo fi ba a tọrọ aforiji lọwọ Ọọni, aṣiṣe ni Sunday Igboho ṣe pẹlu ọrọ to sọ yẹn, bẹẹ ko ṣeni ti ko le ṣe aṣiṣe, ki Kabiesi fori ji i.
“O ṣe pataki ki a sọ ọ lasọye pe ko si Ọọni Ile-Ifẹ kan, yala awọn to ti waja, tabi eyi to wa nipo nisiniyii to ṣẹru Fulani ri, awọn ọba wa ni Ile-Ifẹ ki i ṣe ojo rara. Bakan naa ni Gomina Ṣeyi Makinde paapaa ki i ṣe ọlẹ ti ko ni i le sọ ootọ nibi to ba yẹ. Ọrẹ mi ti mo mọ daadaa ti ko ni i dọbalẹ fẹnikan ni, ka ma ti i waa sọ iran Fulani. Gbogbo wa pata la mọ iṣẹ takuntakun ti Sunday Igboho n ṣe, bẹẹ lo jẹ iwuri nla fun gbogbo ọmọ Yoruba nile ati lẹyin odi.”
Tẹ o ba gbagbe, Sunday Igboho ti bu ẹnu atẹ lu bi Ọọni Ile-Ifẹ, Ọba Adeyẹye Ogunwusi, ko ṣe sọ ohun ti oju awọn ọmọ Yoruba n ri lọwọ awọn Fulani darandaran nilẹ Yoruba lasiko to ṣepade pelu Aarẹ Muhammadu Buhari. Bakan naa lo bu ẹnu atẹ lu Gomina Ṣeyi Makinde, Aṣiwaju Tinubu atawọn agbaagba Yoruba kan pe wọn ko sọ bọrọ ṣe jẹ fun Aarẹ. Eyi lo mu Sunday Igboho pe wọn ni ẹru Fulani nigba to ba awọn ọmọ Yoruba ti wọn wa loke okun ṣepade lori ẹrọ alatagba.