Ibọn pa meji ninu awọn to fọle itaja n’Ijẹbu-Ode, wọn mu ọkan laaye

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹ́òkúta

Ile itaja nla ti wọn ti n ta nnkan eelo ile ati foonu ni ibi kan ti wọn n pe ni Fastlink, lagbegbe Oyingbo, n’Ijẹbu-Ode. Afi bawọn ole ṣe ya wọbẹ loru Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kẹta, oṣu keji yii, ti wọn tun fija pẹẹta pẹlu awọn ọlọpaa, ti meji ninu wọn si dagbere faye lọwọ ibọn.

Awọn kan ni wọn ta teṣan ọlọpaa Igbeba, n’Ijẹbu-Ode, lolobo pe awọn ole ti wọ ile itaja naa tibọn-tibọn, wọn si ti bẹrẹ si i ko wọn lọja.

Awọn ọlọpaa pe ikọ fijilante So-Safe lọwọ, wọn jọ lọ sile itaja naa, ṣugbọn niṣe lawọn ẹruuku ọhun ṣina ibọn bolẹ, ti wọn doju ija kọ awọn ọlọpaa to fẹẹ di wọn lọwọ.

Ninu idojukọ yii lawọn meji ti dero ọrun, nigba ti ibọn awọn ọlọpaa ba wọn. Nibi tawọn yooku si ti n sa lọ lọwọ ti ba ọ̀kan ninu wọn to pe ara ẹ ni Isiaka Yakubu, ẹni ọdun mejidinlọgbọn.

 

Isiaka sọ pe ọmọ ipinlẹ Zamfara loun, ṣugbọn ipinlẹ Eko loun atawọn ẹgbẹ oun yii ti waa jale n’Ijẹbu-Ode.

Leave a Reply