Fayoṣe bẹ igbakeji gomina Ondo, o ni ko pada sinu ẹgbẹ PDP

Jide Alabi

Ọgbẹni Peter Ayọdele Fayoṣe ti rọ Igbakeji gomina ipinlẹ Ondo, Agboọla Ajayi, lati pada sinu ẹgbẹ oṣelu PDP.

Ọgbẹni Lere Ọlayinka, ẹni ti i ṣe agbẹnusọ fun gomina ipinlẹ Ekiti tẹlẹ, Peter Ayọdele Fayoṣe, lo fi ọrọ ọhun sita.

Lasiko ti igbakeji gomina Ondo ṣabẹwo si Fayoṣe niluu ẹ, ni Afao Ekiti, lo rọ Agboọla pe ko pada sinu ẹgbẹ ọhun.

Lasiko ibo gomina to kọja l’Ondo ni Agboọla Ajayi dije labẹ asia ẹgbẹ oṣelu Zenith Labour Party fun ipo gomina, ṣugbọn ti ko rọwọ mu.

Fayoṣe ti sọ pe o ṣe pataki fun ọkunrin naa lati fọwọsowopọ pẹlu awọn agbaagba ẹgbẹ, ko si pada sinu ẹgbẹ oṣelu ọhun, ki awọn le jọ gbe e delẹ ileri, nitori eekan pataki ni igbakeji gomina ọhun ti wọn ba n sọ nipa oloṣelu l’Ondo.

Bakan naa lo ni ko gbagbe ohun to ti lọ, ko si jẹ ki awọn tẹ siwaju, nitori ọjọ ọla ti ọkunrin naa ni ninu oṣelu.

Agboọla Ajayi ko ṣai dupẹ lọwọ Fayoṣe, paapaa fun ipa to n ko ninu eto oṣelu nilẹ Yoruba ati ni Naijiria lapapọ. Bakan naa lo sọ pe idi ti oun fi wa si Afao Ekiti niru asiko ọhun ni lati ki i ku oriire ọjọọbi ọgọta ọdun.

O ṣapejuwe Fayoṣe gẹgẹ bii ẹni ti oun bọwọ fun pupọ, bẹẹ lo ṣeleri pe oun ko ni i fi ọdọ ẹ silẹ nigba kan, nitori pe oloootọ eeyan kan ti ko ni i fi dudu pe funfun ni.

 

Leave a Reply