Monisọla Saka
Gomina ipinlẹ Ekiti tẹlẹ, to tun jẹ ọmọ ẹgbẹ oṣelu PDP, ti kọ lẹta kan si Aṣiwaju Bọla Ahmed Tinubu lori eto idibo abẹle ẹgbẹ wọn ti yoo waye lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii, ati ewu to wa nibẹ fun ọkunrin oloṣelu yii.
Ninu lẹta to gba ori ẹrọ ayelujara kan, eyi ti gomina Ekiti naa fọwọ si funra rẹ lo ti kọ ọ pe:
Tinubu mi ọwọn,
Jẹ ki n bẹrẹ lẹta yii si iwọ gangan alara, ti mo ri gẹgẹ bii aṣaaju ati ọkan ninu awọn oguna gbongbo ilẹ Yoruba; lẹta mi naa le ma jọju, paapaa ju lọ nitori awọn nnkan to wa ninu ẹ, eyi temi fẹẹ gbe kalẹ gẹgẹ bii ọmọ Yoruba, ṣugbọn ti ki i ṣe bii oloṣelu bayii.
Bakan naa ni mo tun fẹẹ sọ ọ fun atẹnumọ pe emi ki i ṣe ọmọ ẹgbẹ APC, n o si le jẹ ọmọ ẹgbẹ naa laelae.
Mo n kọ lẹta yii ninu iwoye temi ati ewu ti mo ṣakiyesi pe o rọ mọ iwọ alara lori ọla.
Ọkan lara awọn okodoro ọrọ ti ko ni wa ka tẹ ninu ni awọn ọrọ ti o sọ ni Abẹokuta, leyii to fi han gbangba pe o ri ewu oṣelu, eyi to mu ki o fara ya. Eleyii gan-an lo bi iwe ti mo n kọ si ọ yii.
Bakan naa ni mo tun ka gbogbo iha ti awọn alatilẹyin rẹ nidii oṣelu lati Guusu ati Ariwa kọ si ọrọ naa. Iha ti wọn kọ yii kọ mi lominu fun ọ ati fun igbesi aye rẹ. Lẹẹkan si i, mo ri ewu!
Gẹgẹ bii ẹni to ni imọ daadaa nipa Itan (History), aṣaaju wa pataki nni, Oloye Ọbafẹmi Awolọwọ, ati ẹni ti awọn eeyan gba pe oun lo jawe olubori eto idibo June 12, 1993, Alaaji Moshood Kaṣhimawo Ọlawale, ti awọn ti wọn n pe ni ‘alagbara nidii oṣelu’ mu lọ si Golgotha lati pa. O da mi loju pe irufẹ awọn eeyan bẹẹ yoo gba ọ niyanju pe ki o ma kọbi ara si imọran mi yii.
Beeyan ba wo awọn ohun to foju han to n lọ nigboro bayii, ti mo ba maa sọrọ lori rẹ, sa, mo ri yin gẹgẹ bii ẹni to n luwẹẹ ninu iji agbami oṣelu ẹgbẹ yin. Bẹẹ ni wọn ti n mura silẹ fun ohun ti o maa sọ ati eyi ti o maa ṣe, wọn si ti wa ni igbaradi lati ṣe irufẹ ohun ti wọn ṣe fun Awolọwọ ati Abiọla fun ọ.
Ṣugbọn o ṣe ni laaanu pe ijọba rẹ ti pin yẹlẹyẹlẹ, ta a ba maa fi oju ohun to ṣẹlẹ ni Abẹokuta wo o.
Imọran mi:
Iwe owe, ori kejilelogun, ẹsẹ kẹta, (eyi ti wọn ti tu si ede Yoruba ti Goodnews) ni, “awọn ọlọgbọn eniyan yoo ri wahala to n bọ, wọn yoo si yẹra fun un, ṣugbọn omugọ eniyan yoo fẹsẹ ara wọn rin lọ ko sinu rẹ”.
Lẹẹkan si i, Aṣiwaju, ko ma baa si aṣigbọ, ma a duro nibi yii na, ki n le fun yin laaye lati gbe igbesẹ, yala eyi to daa ni o, tabi eyi ti ko daa, gẹgẹ bi ọlọgbọn agbalagba bi tiyin yii.
Mo fadura sin yin.
Ayọdele Fayoṣe,
Gomina ipinlẹ Ekiti (ọdun 2003-2006, ati 2014 si 2018)