Faith Adebọla, Eko
Ẹjọ ifipa ba ni lo pọ, iṣekuṣe ati hihuwa aidaa pẹlu ọmọbinrin ti ko ti i tojuubọ, eyi ti wọn fi kan gbajugbaja adẹrin-in poṣonu nni, Ọlanrewaju James Omiyinka, tawọn eeyan mọ si Baba Ijẹṣa, ti gbọna mi-in yọ wayi. Baba Ijẹṣa ti ṣalaye ni kootu pe ere tiata lasan loun ati ọmọbinrin ti wọn fẹsun rẹ kan oun naa jọ n ṣe lọjọ naa, ati pe olufisun oun, Damilọla Adekọya, tawọn eeyan mọ si Princess, lo sọ pe koun ṣe gbogbo ohun toun ṣe.
Bakan naa lafurasi ọdaran ọhun jẹwọ pe ọrọ ifẹ wa laarin oun ati olufisun oun, Princess, o ni ololufẹ oun ni, awọn ti jọ laṣepọ daadaa sẹyin, tawọn fẹnu ko ara awọn lẹnu, o si ti sun yara oun mọju lọpọ igba.
Ọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kẹrin, oṣu kẹta yii, ni Baba Ijẹṣa tu pẹrẹpẹrẹ ọrọ naa niwaju Adajọ Oluwatoyin Taiwo, lasiko igbẹjọ rẹ ni kootu ti wọn ti n gbọ ẹsun akanṣe ati iwa ọdaran abẹle, eyi to fikalẹ siluu Ikẹja, nipinlẹ Eko.
Agbẹjọro rẹ, Dada Awoṣika, lo beere pe kile-ẹjọ naa fun onibaara oun laaye lati wi tẹnu ẹ lori awọn ẹsun ti wọn fi kan an, ko si sọ bọrọ ṣe jẹ gan-an lọjọ ti iṣẹlẹ naa waye, ladajọ ba yọnda fun un.
Baba Ijẹṣa ni: “Lọjọ kọkandinlogun, oṣu kẹrin, ọdun 2021, Princess fi atẹjiṣẹ ṣọwọ sori foonu mi pe oun fẹẹ ya fiimu tuntun kan, ipa toun si fẹ ki n ko ninu fiimu naa ni ololufẹ, o loun diidi yan ipa yii fun mi ni lati jẹ kawọn eeyan le mọ pe mo le kopa mi-in yatọ si ti alawada, ninu ere. O ni itan naa da lori bi ọdọkunrin to jẹ ololufẹ ọmọbinrin kan ṣe fẹẹ fipa ba a lopọ, ṣugbọn ọna ọtọ loun fẹẹ gbe ere naa gba.”
Lasiko yii, agbẹjọro Baba Ijẹṣa, ko gbogbo awọn iwe to ṣafihan atẹjiṣẹ ati ijiroro to waye laarin Princess ati onibaara rẹ siwaju adajọ gẹgẹ bii ẹri pe ododo ni Baba Ijẹṣa n sọ, adajọ si gba awọn ẹri naa wọle, lọkunrin naa ba n ba awijare rẹ lọ.
“Mo beere lọwọ Princess pe ibo la ti maa ya fiimu naa, o fesi pe ki n ṣaa maa bọ nile oun, mo ni mo ti gbọ. Ki n too wọle rẹ, Princess lo kọkọ pade mi ni bakoni ile naa, o sọ fun mi pe ipinlẹ Eko lo ni iṣẹ naa, awọn loun fẹẹ ya fiimu ọhun fun, ati pe ipinlẹ Eko fẹẹ sọ oun di aṣoju wọn lati ṣekilọ lori iwa ṣiṣe ọmọde niṣekuṣe ni.
“O ni ki n ṣaa ronu agbekalẹ to daa ti ma a lo fun itan naa ati ipa to fẹ ki n ko. Nigba ti mo wọle, mo sọ fun un pe ile naa ti ṣookun ju, o ni kemi ati ọmọbinrin naa ṣi maa ba ifidanrawo ipa ti a maa ko niṣo, o loun maa fi foonu ya wa. Princess sọ fun mi pe ki n kiisi ọmọbinrin naa, ki n si mu ọyan ẹ, o ni tori ẹ lọmọbinrin naa ṣe wọṣọ to wa lọrun ẹ, ki ipa ta a fẹẹ ko naa le rọrun, ati pe oun maa jade fungba diẹ, ki ọmọbinrin ọhun le ṣe daadaa tori oju le fẹẹ maa ti i, toun ba wa nibẹ.
‘‘Oluwa mi, gbogbo nnkan tẹ ẹ wo ninu fidio ti wọn fi fẹsun kan mi yẹn, a wulẹ n ṣe fiimu lasan ni, ki i ṣe tootọ. Ẹ ṣewadii mi, to ba di ọrọ pe kikopa ninu fiimu, mo maa n hara gaga ni, mo le pa ara mi tori ẹ, Princess lo ya fidio yẹn, oun lo ṣe adari ere, oun lo sọ ba a ṣe maa ṣe e.
Lẹyin atotonu wọn, Onidaajọ Oluwatoyin Taiwo sun igbẹjọ to kan si ọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kọkanla, oṣu Kẹta yii.