Gbogbo ọmọ Ekiti lo wa lẹyin Tinubu lati ri i pe o wọle idibo ọdun 2023- Ewi Ado-Ekiti

Taofeek Surdiq, Ado-Ekiti

Gomina ipinlẹ Eko tẹlẹ, Asiwaju Bọla Tinubu, ti ṣalaye pe idi pataki toun ṣe fẹẹ dije fun ipo aarẹ lọdun 2023 ni lati da ireti awọn ọmọ orilẹ-ede yii pada, ati lati tun orilẹ-ede yii ṣe ki ayipada le de baa.

Tinubu sọ pe Naijiria nilo olori ati adari to ni imọ ati oye lakooko yii lati le ko gbogbo ọmọ Naijiria jọ lati gbogun ti eto aabo, ti yoo si tun tun ọrọ aje orilẹ-ede yii ṣe ti yoo fi wulo fun gbogbo wa.

Aṣiwaju sọrọ yii l’Ọjọbọ, Tọside, ọsẹ yii nipinlẹ Ekiti, lakooko to ṣe ipade pẹlu awọn ọba ipinlẹ naa ati abẹwo lati fi erongba rẹ lati dije dupo aarẹ lọdun 2023 han.

Gomina ipinlẹ Eko oun tẹlẹri ọhun ti Igbakeji gomina ipinlẹ Ekiti, Otunba Bisi Ẹgbẹyẹmi, ki kaabọ sibi ipade naa ti wọn ṣe ni gbọngan ile awọn ọba ipinlẹ Ekiti to wa l’Oke Barike, l’Ado-Ekiti.

Awọn ẹgbẹ SWAGA ati adari wọn, Ọmọọba Dayọ Adeyẹye, naa ko gbẹyin nibi ipade ọhun.

Awọn ọba alaye naa ti Oniṣan ti Iṣan-Ekiti, Ọba Gabriel Adejuwọn, jẹ alaga wọn, ni Tinubu ṣalaye fun pe oun wa si ipinlẹ Ekiti lati sọ ero ọkan oun fun wọn lati dije fun ipo aarẹ lọdun 2023, ati lati le gba adura ati atilẹyin wọn.

Gẹgẹ bo ṣe sọ, ọkunrin ti wọn maa n pe Jagaban yii ni oun jẹ ọkan lara awọn to ja fun ominira ijọba awa-ara-wa lorilẹ-ede Naijiria. O fi kun un pe o jẹ ohun iyalẹnu pe ijọba awa-ara-wa ko ti i dagba soke pẹlu bii eto aabo ṣe bajẹ, bakan naa ni eto ẹkọ ko tẹsiwaju.

O ṣalaye pe eto ọgbin ko ni itẹsiwaju, nitori o yẹ ki orilẹ-ede Naijiria ti maa ko ire oko ati ohun ọgbin wa ranṣẹ si oke okun fun tita.

O ni oun pinnu lati dije ki ala ọjọ iwaju awọn ọdọ orilẹ-ede Naijiria le di mimuṣẹ ati ki ọjọ ọla orilẹ-ede Naijiria le dara fun awọn ọdọ lọjọ iwaju.

O fi kun un pe idi pataki miiran ti oun ṣe fẹẹ dije ni lati le jẹ ki Naijiria wa ni iṣọkan, ati ki igbega le de ba gbogbo ẹka to wa lorilẹ-ede yii.

Nigba to n sọrọ lakooko to gba a lalejo rẹ laafin rẹ, Ewi ti Ado-Ekiti, Oba Rufus Adeyẹmọ Adejugbe, sọ pe inu oun dun gidigidi pe Oloye Bọla Tinubu jade lati dije, o fi kun un pe gbogbo ọmọ ipinlẹ Ekiti lo wa lẹyin rẹ lati ri i pe o wọle ninu eto idibo ọdun 2023.

Leave a Reply