Fitila ati Imọlẹ fibọn gbowo lọwọ oni-POS ni Ketu

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

Ọjọ Abamẹta, Satide, to kọja yii, ti i ṣe ọjọ kejilelogun, oṣu karun-un, lọwọ tẹ awọn gende meji yii, Balogun Haruna(Fitila) ati Imọlẹ Noah, pe wọn fi ibọn gba ẹgbẹrun lọna ọgọta naira (60,000) lọwọ obinrin oni-Pos kan torukọ ẹ n jẹ Ajọsẹ Bilikisu, lagbegbe Ketu Adiowe, nijọba ibilẹ Ado-Odo Ọta, nipinlẹ Ogun. Orukọ awọn meji naa ni.

Mẹrin tilẹ ni wọn gẹgẹ bi DSP Abimbọla Oyeyẹmi to fidi iṣẹlẹ yii mulẹ ṣe wi, o ni awọn meji sa lọ ninu wọn ni.

Nigba to n ṣalaye siwaju, Alukoro ọlọpaa Ogun yii sọ pe yatọ si owo ti wọn gba lọwọ Bilikisu, wọn tun gba foonu Android meji lọwọ rẹ pẹlu ìdì kọkọrọ kan.

Wọn n jale ọhun lọwọ ni olobo ta wọn ni teṣan ọlọpaa Idanyin, ti DPO Ọlayinka Kuyẹ atawọn eeyan ẹ fi sare lọ sibẹ. Ṣugbọn awọn meji raaye sa lọ ninu awọn adigunjale mẹrin naa, wọn si gbe awọn nnkan ija ti wọn fi n ṣọṣẹ lọ pẹlu.

Fitila ati Imọlẹ nikan lọwọ ba, wọn si jẹwọ pe loootọ lawọn yọbọn si obinrin oni-POS naa, awọn si gba owo ati foonu pẹlu kọkọrọ rẹ lọ. Fitila tilẹ jẹwọ pe ọmọ ẹgbẹ okunkun Ẹyẹ loun.

Ọta ibọn ti wọn ti yin lawọn ọlọpaa ba lọwọ wọn.

Wọn ti ko wọn lọ sẹka itọpinpin, CP Edward Ajogun si ti paṣẹ pe ki wọn wa awọn meji to sa lọ naa ri.

Leave a Reply