Ọlawale Ajao, Ibadan
Oludije labẹ ẹgbẹ oṣelu All Progresives Congress, APC, ninu idibo abẹle ẹgbẹ oṣelu ọhun nipinlẹ Ọyọ, Ọnarebu Sẹmiu Fọlarin, ti binu fi ẹgbẹ oṣelu Onigbaalẹ silẹ, o ni ninu ẹgbẹ oṣelu New Nigeria People’s Party (NNPP) loun yoo ti dupo bayii.
Ọnarebu Fọlarin, to jẹ oludasilẹ ajọ Opeyemi Sẹmiu Foundation (OSF), lo n dije fun ipo aṣofin ẹkun idibo Ido, nileegbimọ aṣofin ipinlẹ Ọyọ labẹ ẹgbẹ oṣelu APC.
Ṣaaju lo ti dupo alaga kansu ijọba ibilẹ Ido lorukọ ẹgbẹ oṣelu Zenith Labour Party. Wọn loun lo ni ibo to pọ ju lọ ninu idibo ọhun to waye ninu oṣu Karun-un, ọdun 2021, ṣugbọn ti ko le depo naa nitori ti wọn lẹgbẹ PDP to n ṣakoso ijọba ipinlẹ yii fọwọ ọla gba a loju, ti wọn si gbe ọmọ ẹgbẹ wọn sori aleefa.
O wa lara awọn to dupo aṣofin ẹkun idibo Ido ninu idibo abẹle ẹgbẹ APC to waye laipẹ yii, ṣugbọn ti ọsan ko so didun fun un mu nibi eto idibo ọhun. Ṣugbọn lọsẹ to kọja lọkunrin naa deede kede pe oun ko ṣegbẹ Onigbaalẹ mọ.
Nitori ọna ti wọn gba dibo abẹle ẹgbẹ naa lasiko idibo naa lọkunrin alakooso ajọ OSF yii ṣe sa kuro ninu ẹgbẹ oloṣuṣu ọwọ, o ni magomago wa ninu ọna ti wọn gba ṣeto idibo ọhun.
Gẹgẹ bo ṣe sọ, “Emi Sẹmiu Ọpẹyẹmi Fọlarin fi asiko yii kede pe mi o ṣẹgbẹ APC mọ. Lẹyin ti mo ti ṣepade pẹlu awọn alatilẹyin mi, mo ti dara pọ mọ ẹgbẹ oṣelu to ni ọjọ iwaju, ẹgbẹ to le mu ala mi wa si imuṣẹ ninu idibo ọdun 2023 ni.”
O ni pẹlu ipade ti oun ṣe pẹlu Alhaji Bisi Ọlọpọeyan ti i ṣe adari ẹgbẹ NNPP ni gbogbo ilẹ Yoruba, oun nigbagbọ pe nnkan yoo ṣẹnuure fun oun ninu idibo ọdun to n bọ.
Ni bayii, ẹgbẹ oṣelu tuntun naa ti fun Fọlarin ni tikẹẹti lati dupo aṣofin ẹkun idibo Ido nileegbimọ aṣofin ipinlẹ Ọyọ ninu idibo ọdun 2023.