Faith Adebọla, Eko
Boya ni gomina ipinlẹ Plateau tẹlẹ, Ọmọwe Joshua Dariye, le gbagbe ọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kejila, oṣu yii, bọrọ, tori ọjọ naa ni gbogbo igbiyanju rẹ lati jajabọ ninu ẹwọn ọdun mẹrinla to n jiya rẹ ̀lọwọ fori ṣanpọn, ile-ẹjọ to ga ju lọ nilẹ wa (Supreme court) da ẹjọ ko-tẹ-mi-lọrun rẹ nu, wọn ni ko lọọ fara balẹ pari ẹwọn ọdun mẹwaa ti wọn da fun un ni.
Adajọ Abilekọ Mary Odili to ṣaaju igbimọ idajọ ẹlẹni marun-un tile-ẹjọ giga naa, lo gbe idajọ yii kalẹ lowurọ ọjọ Ẹti, o ni awọn maraarun ni wọn panu-pọ lori idajọ naa, ko sẹni to ni ero to yatọ. O lawọn ti fara balẹ yẹ gbogbo ẹri ti wọn ko kalẹ siwaju awọn ile-ẹjọ to ti n gbọ ẹjọ naa bọ, gbogbo atotonu ati ẹsun ti olupẹjọ fi kan olujẹjọ, Ọgbẹni Dariye, bẹẹ ni wọn lawọn tun yẹ awijare olujẹjọ wo, awọn si ṣagbeyẹwo awọn idajọ tawọn ile-ẹjọ to gbọ ẹsun naa ṣaaju gbe kalẹ, lati mọ bi gbogbo nnkan wọnyi ṣe tẹwọn si, ati bo ṣe ba ofin ilẹ wa mu si.
Ni abarebabọ, awọn adajọ naa ni eyi to pọ ju lọ ninu awọn ẹsun ti wọn fi kan olujẹjọ yii lo jẹbi wọn, wọn lawijare ẹ ko muna doko rara, awawi ni ti ko lẹsẹ nilẹ lo n ṣe.
Wọn ni bile-ẹjọ ko-tẹ-mi-lọrun ṣe ṣatunṣe si idajọ ẹwọn ọdun mẹrinla tile-ẹjọ giga kan ti kọkọ sọ olujẹjọ naa si, ti wọn si din ẹwọn ọhun ku si ọdun mẹwaa ba ofin mu, wọn lo wa pa bẹẹ. WỌn lasiko ti wọn ni ko bẹrẹ ẹwọn naa ba ofin mu, awọn o ri aleebu kan ninu idajọ wọn.
Pẹlu idajọ ile-ẹjọ giga ju lọ yii, ipo sẹnetọ ti gomina ana naa wa nile-igbimọ aṣofin agba l’Abuja ti dohun itan, idajọ naa sọ pe ko kangara ẹ kuro nile aṣofin naa kia.
Tẹ o ba gbagbe, ajọ to n gbogun tiwa ibajẹ, iwa ajẹbanu, jibiti lilu ati ṣiṣe owo ilu mọkumọku nilẹ wa, Economic and Financial Crimes Commission (EFCC) lo ti n ba Joshua Dariye ṣẹjọ lori ẹsun mẹtalelogun ti wọn fi kan an, awọn ẹsun naa da lori pe o dari owo ilu ti aropọ rẹ jẹ biliọnu kan, miliọn lọna ọgọrun-un naira (#1.162) sapo ara ẹ, wọn ni ko fowo naa ṣe iṣẹ ilu, niṣe ni Dariye fowo ṣara rindin. Wọn tun fẹsun kan an pe o lo ipo ati agbara to ni gẹgẹ bii gomina ipinlẹ Plateau nigba naa lati huwa aidaa, wọn lo ṣi agbara lo.
Adajọ Adebukọla Banjoko tile-ẹjọ ijọba apapọ l’Abuja lo ti kọkọ gbọ ẹjọ naa, o si gbe idajọ rẹ kalẹ lọjọ kejiila, oṣu kẹfa, ọdun 2018, pe Dariye jẹbi mẹẹẹdogun ninu awọn ẹsun naa, wọn ni ko lọọ fẹwọn ọdun mẹrinla jura.
Olujẹjọ naa pe ẹjọ ko-tẹ-mi-lọrun, o ni ile-ẹjọ naa ṣojuṣaaju ni, wọn ko gbọ ẹjọ oun daadaa to, o ni ki wọn ba oun yi idajọ naa pada, ki wọn si da oun lare, ṣugbọn ile-ẹjọ ko-tẹ-mi-lọrun, lẹyin awọn awijare ati atotonu olujẹjọ ati olupẹjọ, Adajọ Stephen Adah gbe idajọ kalẹ lọjọ kẹrindinlogun, oṣu kọkanla, ọdun 2018, kan naa, wọn ni ẹyọ meji pere ninu ẹsun mẹẹẹdogun ti wọn ni olujẹjọ naa jẹbi ẹ lawọn yoo da nu, wọn ni mẹtala ninu awọn ẹsun naa foju han rekete. Latari eyi, wọn dajọ pe ki Dariye lọọ ṣẹwọn ọdun mẹwaa dipo mẹrinla.
Dariye tun pẹjọ ko-te-mi-lọrun sile-ẹjọ giga ju lọ, eyi ti idajọ rẹ ṣẹṣẹ waye lọjọ Ẹti yii. Pẹlu idajọ yii, o ti fidi mulẹ pe Joshua Chibi Dariye yoo pari ẹwọn ọdun mẹwaa ti wọn da fun un latari ẹsun ikowojẹ.