Oluyinka Soyemi, Ado-Ekiti
Awọn ọlọpaa ti wọ awọn ọkunrin meji kan, Friday Ọmọniyi ati Shehu Aliyu, lọ siwaju Majisreeti-agba Adefunkẹ Anoma tile-ẹjọ Majisreeti ilu Ado-Ekiti bayii, wọn ni wọn yoo jẹjọ gbigba ẹru ole ati ṣiṣe oniduuro fun ẹni to jale.
Inspẹkitọ Oriyọmi Akinwale ṣalaye ni kootu pe Friday, ẹni ọdun mejidinlogoji, lo gba mọto Toyota Sienna ti nọmba ẹ jẹ APP 03 EP lọwọ Mustapha Shehu, lọjọ kẹrin, oṣu keji, ọdun yii. O ni mọto towo ẹ to ẹgbẹrun lọna ẹgbẹta naira (N600,000) yii lo jẹ ti ẹnikan toun n jẹ Atiku Malami.
O sọ siwaju pe iwadii awọn ọlọpaa fidi ẹ mulẹ pe olujẹjọ naa gba mọto ọhun lọsan-an ọjọ naa lọwọ Mustapha, bẹẹ o mọ pe o ji i ni, idi niyi to fi jẹbi iwa to hu.
Ọlọpaa naa ni nigba to di ọjọ kọkanla, oṣu yii, Shehu Aliyu toun jẹ ẹni ọdun marundinlaaadọrin lọ si ọfiisi ọga ọlọpaa agbegbe Ado-Ekiti lati ṣe oniduuro fun Mustapha to jẹ eeyan ẹ, bẹẹ o mọ pe o ji mọto tawọn ọlọpaa tori ẹ mu un ni.
Akinwale tun fidi ẹ mulẹ ni kootu pe iwa ti oniduuro naa hu fi han pe o mọ-ọn-mọ fẹẹ da ẹjọ ọhun ru ni, ko si gba ominira fun ọdaran to waa duro fun.
Awọn ẹsun wọnyi ni Akin wale sọ pe Friday ati Shehu Aliyu jẹbi wọn labẹ ofin iwa ọdaran tipinlẹ Ekiti, ileeṣẹ ọlọpaa si ni awọn ẹlẹrii ti yoo sọ bi ọrọ naa ṣe jẹ nile-ẹjọ.
Nigba ti wọn beere ọrọ lọwọ awọn olujẹjọ mejeeji, wọn ni awọn ko jẹbi ẹsun gbigba ẹrun ole ati ṣiṣe oniduuro fun ẹni to jale.
Lẹyin naa ni Amofin Michael Ọlalẹyẹ to jẹ lọọya Friday ati Amofin Emmanuel Fọlayan toun duro fun Shehu Aliyu rọ kootu lati fun wọn ni beeli lọna irọrun, wọn ni awọn afurasi ọhun ko ni i sa lọ.
Majisreeti-agba Adefumike Anoma gba si awọn lọọya naa lẹnu, o faaye beeli ẹgbẹrun lọna ọgọrun-un naira (N100,000) silẹ fun ẹnikọọkan wọn pẹlu oniduuro kan, bẹẹ lo ni igbẹjọ yoo bẹrẹ lọjọ karun-un, oṣu to n bọ.