Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Iroyin to ALAROYE lọwọ bayii fidi rẹ mulẹ pe awọn Fulani agbebọn ti ji awọn arinrin-ajo ti ẹnikẹni ko ti i mọ iye wọn gbe lagbegbe Akede, loju ọna Oṣogbo si Ikirun.
Aarọ ọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu Kẹta, ọdun yii, la gbọ pe wọn da awọn arinrin-ajo naa lọna, ti wọn si ko wọn lọ sinu igbo kan laarin Oṣogbo si Iragbiji.
Ṣaaju iṣẹlẹ yii ni ori ti ko ọkunrin birikila kan, Moses Taiwo, ti wọn ji gbe lagbegbe Dagbolu, laarin Oṣogbo si Ikirun, l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu Kẹta, ọdun 2023.
Ni ti Ọgbẹni Taiwo, o ni ede Fulfulde ni awọn mẹrin ti wọn dihamọra ogun naa kọkọ n sọ, ṣugbọn nigba to ya ni wọn bẹrẹ si i sọ ede Yoruba.
O ni awọn meji lawọn ajinigbe naa ko, lẹyin ti wọn si gba gbogbo owo ọwọ awọn ni wọn de awọn lọwọ, nigba ti wọn si n ko awọn lọ sinu igbo ni ẹni keji sa mọ wọn lọwọ.
Ọkunrin yii ni wọn fi foonu oun beere miliọnu mẹwaa Naira lọwọ ọmọ oun, ṣugbọn nigba ti ẹni keji oun ti sa lọ ni wọn bẹrẹ si i lu oun lalubami, nigba ti wọn si kiyesi i pe ẹmi ti fẹẹ bọ lara oun ni wọn fi oun silẹ.
Ni ti ijinigbe ti ọjọ Ẹti, Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa Ọṣun, Yẹmisi Ọpalọla, sọ pe awọn ko ti i mọ iye awọn arinrin-ajo ti wọn ji gbe, ṣugbọn wọn ti ri dẹrẹba ọkọ naa pẹlu ọkọ rẹ.
O ni iṣẹ ti bẹrẹ lori igbesẹ lati wa awọn eeyan naa ri, nitori gbogbo awọn ẹṣọ alaabo ni wọn ti wa ninu igbo aarin Osogbo si Iragbiji ati Ibokun, lati ṣawari awọn eeyan naa.