Fulani darandaran kọju ija sawọn Amọtẹkun l’Ondo

Dada Ajikanje

Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii, ni awọn Fulani darandaran kan kọju ija si awọn ikọ Amọtẹkun ni Abule Osi, njọba ibilẹ Ariwa Akurẹ, nipinlẹ Ondo.

ALAROYE gbọ pe awọn eeyan agbegbe naa lo ranṣẹ pe wọn nitori bi awọn darandaran naa ṣe fi maaluu jẹ oko wọn. Lasiko ti awọn Amọtẹkun n gbiyanju lati yanju wahala naa lawọn Fulani yii doju ija kọ wọn.

Ọga ikọ Amọtẹkun naa nipinlẹ Ondo, Oloye Adetunji Adelẹyẹ, ṣalaye pe awọn eeyan abule naa lo pe awọn nipe pajawiri lori bi awọn Fulani ṣe da maaluu wọ inu oko wọn, ti wọn si jẹ awọn ire oko wọn.

Eyi lo mu ki oun ran awọn eeyan awọn lọ sibẹ. Nigba ti wọn debẹ ti wọn ba awọn maaluu yii ninu oko ni wọn pe awọn darandaran ọhun. Ṣugbọn niṣe ni awọn Fulani naa kọju ija si awọn eeyan naa pẹlu ọbẹ atawọn ohun ija mi-in.

Adelẹyẹ ni ọwọ tẹ ọkan ninu wọn torukọ rẹ n jẹ Abdulkadir Muhammed, oogun abẹnugọngọ ati awọn ohun ija oloro lawọn si ba lọwọ rẹ. Bẹẹ lo ni awọn ti gbẹsẹ le maaluu mẹrindinlogun.

 

Leave a Reply