Fun igba akọkọ, Akeredolu yan obinrin gẹgẹ bii akọwe ijọba l’Ondo

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

 

Gomina Rotimi Akeredolu ti yan Abilekọ Ọladunni Odu gẹgẹ bii akọwe ijọba ipinlẹ Ondo tuntun.

Ikede yii waye ninu atẹjade ti Akọwe iroyin fun gomina, Richard Ọlatunde, fi sitav by lọsan-an Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii.

Odu ni obinrin akọkọ ti yoo di ipo yii mu lati bii ọdun marundinlaaadọta ti wọn ti da ipinlẹ Ondo silẹ.

Ọmọ bibi ilu Idepe, nijọba ibilẹ Okitipupa, ni Abilekọ Odu, o kẹkọọ gboye gẹgẹ bii amofin ni fasiti ijọba apapọ to wa niluu Eko.

Lati bii ọdun mẹta sẹyin ni wọn ti yan an gẹgẹ bii alaga eto ẹkọ kariaye (SUBEB) ẹka tipinlẹ Ondo.

Ipo yii lo si di mu titi di Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii, ti wọn kede rẹ gẹgẹ bii akọwe ijọba ipinlẹ Ondo.

Abilekọ Ọladunni Odu

 

Leave a Reply