Gani Adams ni ki wọn gbe kọmiṣanna ọlọpaa Ọyọ kuro, o lobìnrin naa ko jafafa to

 

Ki eto aabo le fẹsẹ rinlẹ daadaaa nipinlẹ Ọyọ, Aarẹ Ọnakakanfo ilẹ Yoruba, Iba Gani Abiodun Ige Adams, ti ke si ọga ọlọ́pàá patapata, Mohammed Adamu, pe ko tete paarọ Kọmiṣanna ọlọ́pàá ipinlẹ ọhun,

Arabinrin Ngozi Ọnadẹkọ. Iba Gani Adams sọ pé ki wọn gbe e kuro nitori ti ọrọ eto aabo ju ohun ti obinrin le wa ni ikapa ẹ nipinlẹ ọhun lọ.

Iba Gani Adams sọ pe niṣe ni ọga ọlọ́pàá yìí n fọwọ oṣelu mu ọrọ eto aabo ipinlẹ naa, ati pe ọrọ aabo ipinlẹ Ọyọ ti mẹhẹ debii pe iwa ijinigbe atawọn iwa ọdaran mi-in ti tubọ pọ si i lagbegbe Oke Ogun ati Ibarapa.

O ni o ṣe pataki ki ileeṣẹ ọlọpaa tete wa ẹni to too koju iṣoro aabo nipinlẹ náà dipo obinrin ti wọn fi ṣolori awọn ọlọpaa ti ko jáfáfá to.

Iba Gani Adams, ninu atẹjade ti Akọwe iroyin rẹ, Kẹhinde Aderẹmi, fi sita lo ti bu ẹnu àtẹ lu bi awọn ọlọpaa ṣe ko awọn ọmọ ẹgbẹ OPC ti wọn mu Wakili tó n da awọn èèyàn laaamu n’Ibarapa ju satimọle.

Bakan naa lo tun bu ẹnu atẹ lu bi ileeṣẹ ọlọpaa ṣe fẹsun kan awọn ọmọ ẹgbẹ OPC mẹtẹẹta pe wọn ṣe dukia onidukia lofo. Gani Adams tun sọ pé irufẹ ẹsun yìí kò ní í ṣai ba ọlọpaa lorukọ jẹ, nitori ẹsun irọ ni wọn fi kan wọn.

Ààrẹ ni òun ti ṣetan bayii lati fi ẹsẹ ofin tọ iya ainidi ti ileeṣẹ ọlọpaa fi n jẹ awọn ọmọ ẹgbẹ OPC ohun.

“Tẹ o ba gbagbe, laipẹ yìí ni Alaafin ilu Ọyọ, Ọba Lamidi Adeyẹmi kẹta, fẹhonu hàn lori ipo ti eto aabo ipinlẹ Ọyọ wa bayii. Ninu ọrọ Alaafin ni Ọba Adeyẹmi ti sọ pe ida aadọrun-un ninu awọn agbẹ to wa ni Oke-Ogun, Ibarapa at’awọn agbegbe mi-in ni wọn kò lè lọ soko wọn mọ nitori ogun Fulani to gba agbegbe ọhun kan.

“Pẹlu ohun ti Kabiesi sọ yìí, o fi hàn pé kò sí ifọkanbalẹ mọ lori eto aabo nipinlẹ Ọyọ. Bakan naa lo buru debii pe awọn èèyàn tawon ọmọ ẹgbẹ OPC mu yìí, awọn olopaa ti tu wọn silẹ, ti wọn sì ti awọn ọmọ ẹgbẹ wa to mú wọn sì atimọle pẹlu ẹsun ti ko fẹsẹ rinlẹ.”

Gani Adams sọ pe ti awọn agbẹ ko ba ri oko wọn dé mọ, nígbà wo ni iyan ounjẹ kò ní í mú.

“Mo n fi asiko yii ke si ọga ọlọ́pàá patapata ati ileeṣẹ ọlọpaa ki wọn tete gbe Arabinrin Ngozi kuro nipinlẹ Ọyọ. Ninu ìwádìí tí mo ṣe, obinrin olopaa yii ko muyanyan to, bẹẹ ni ko jafafa pẹlu.”

Bẹẹ gẹgẹ ni Adams tun ké sí Gomina Ṣeyi Makinde lati fọwọsowọpọ pẹlu ọga ọlọ́pàá patapata ki eto aabo to gbopọn le fẹsẹ mulẹ nipinlẹ Ọyọ, pàápàá lori bi awọn ajinigbe atawọn ọdaran mi-in ṣe n pada sí Òkè ogun.

Awọn èèyàn mẹta tọwọ awọn olopaa tẹ náà ni Awodele Adedigba, Dauda Kazeem, ati Hassan Ramọn. Koko ẹsun mẹfa ni wọn sì ká sì won lẹsẹ.

 

Leave a Reply