Gbenga Daniel darapọ mọ ẹgbẹ APC

Gomina ipinlẹ Ogun tẹlẹ, Ọtunba Gbenga Daniẹl, naa ti darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu APC bayii.

Ninu iwe kan to gbe jade, eyi to fọwọ si, lo ti sọ pe, ‘‘Gbogbo ẹyin ọrẹ ati alabaasiṣẹpọ mi, mo tọrọ aforiji pe n ko tete sọ fun yin pe emi naa ti darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu APC, eyi to ti yẹ ki ẹyin naa maa fura pe mo le ṣe bẹẹ nitori atilẹyin mi fun gomina ipinlẹ Ogun, Dapọ Abiọdun, lasiko eto idibo to kọja.

‘’O ti pẹ ti awọn eeyan ti n yọ mi lẹnu pe ki n waa darapọ mọ ẹgbẹ naa, ṣugbọn gbogbo nnkan gba ọna mi-in laarin wakati mejidinlaaadọta pẹlu bi alaga ẹgbẹ APC ṣe sọ pe oun fẹẹ ṣabẹwo sọdọ mi ni Asọludẹrọ pẹlu awọn gomina ẹgbẹ naa mẹta ni Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii.

‘‘Bi eleyii ṣe n lọ lọwọ naa ni Gomina Dapọ Abiọdun sọ pe oun fẹẹ ṣabẹwo sọdọ mi lonii, bẹẹ ni awọn gomina kan naa tun n palẹmọ lati ṣabẹwo sọdọ mi lonii yii kan naa. Ohun ti eyi tumọ si ni pe gbogbo wọn ti ‘mu mi’

‘‘Mo si woye pe niṣe lo yẹ ki n tete sọ fun yin ki iroyin naa too kale-kako, mo dupẹ fun agbọye yin, Ọtunba Gbenga Daniel.’’

Bi gomina Ogun tẹlẹ naa ṣe kọwe to fi sita niyi, ALAROYE si gbọ pe gbogbo eto ti n lọ lati ri i pe gomina tẹlẹ naa forukọ silẹ ninu ẹgbẹ APC ki eto naa too kasẹ nilẹ lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii.

Leave a Reply