Gbese ti mo jẹ ni mo n wa owo rẹ ti mo fi tẹle wọn lọọ jiiyan gbe-Adewale

Ọlawale Ajao, Ibadan

Marun-un lawọn afurasi ajinigbe ọhun, Abọlaji Azeez Aleṣe Bakare (BJ), ọmọ bibi Agọ-Iwoye, ni ipinlẹ Ogun, lolori ikọ naa.  Bi wọn ṣe n jiiyan gbe n’Ibadan ni wọn n pa awọn ara ipinlẹ Ogun paapaa lẹkun jaye. Ọpọlọpọ eeyan ni wọn si ti ji gbe ko too di pe ọwọ tẹ ọkunrin naa pẹlu igbakeji rẹ.

BJ, to jẹ ọga gbogbo wọn patapata naa lawọn ọlọpaa kọkọ mu nibi to ti n jaye ọlọba nileetura kan nigboro Ibadan. Ikọ awọn ọlọpaa kan ta a mọ si eṣu-lẹyin-ọdaran, iyẹn ẹka ti wọn n pe ni Monitoring Unit, nileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ, labẹ akoso CSP Ṣọla Arẹmu, lo lọọ ka jagunlabi mọ ibuba ẹ, ko too di pe wọn ri Adewale Abọlarinwa (Oro) ti i ṣe igbakeji rẹ mu lẹyin iwadii alagbara.

Orukọ awọn mẹta yooku, tọwọ awọn agbofinro ko ti i to ni OJ, Dagunro ati Kẹhinde, ẹni ti wọn tun n pe ni JK.

Ibọn alagbara kan bayii tawọn oloyinbo n pe ni pump action meji lawọn ẹruuku yii n gbe kiri. Awọn ibọn ọhun pẹlu ọta meji ni wọn ba nibuba wọn pẹlu oriṣii ọkọ ayọkẹlẹ mẹjọ ọtọọtọ ti wọn fi owo ti wọn ti gba nibi okoowo ijinigbe wọn ra.

Bakan naa ni wọn ba miliọnu meji ati ẹgbẹrun lọna ẹẹdẹgbẹta Naira (N2.5) lọwọ awọn apanilẹkunjaye yii. Eyi la gbọ pe awọn eeyan yii na ku ninu owo ti wọn gba lọwọ mọlẹbi awọn eeyan ti wọn ji gbe.

Abọlaji, ẹni tawọn ẹgbẹ ẹ mọ si i BJ yii, ati Adewale, ti wọn tun n pe ni Oro, pẹlu awọn mẹta yooku ti wọn ti na papa bora, ni wọn da obinrin kan to n jẹ Atitẹbi Ganiyat lọna loju ọna to ti Fẹlẹlẹ ja sọna Eko s’Ibadan, lasiko ti onitọhun n mu ọmọkunrin rẹ lọ sileewe, ti wọn si ji i gbe tọmọtọmọ lọjọ kejidinlogun, oṣu Kẹjọ, ọdun 2022 yii.

Nigba to n fidi iroyin yii mulẹ fawọn oniroyin lorukọ CP Adebọwale Williams ti i ṣe ọga agba awọn ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ, Alukoro fun ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ naa, SP Adewale Ọṣifẹṣọ, ṣalaye pe ọna ipinlẹ Ogun lawọn afurasi ajinigbe yii gbe wọn lọ ki wọn too wa ọmọọdun mẹjọ naa gunlẹ sẹgbẹẹ titi niluu Ṣagamu. Inu ọkọ jiipu Toyota Highlander ti iya ẹ fi n gbe e lọ sileewe ni wọn jọwọ ẹ si lẹbaa ọna nibẹ, ti wọn si gbe iya ẹ wọnu igbo lọ.

SP Ọṣifẹṣọ sọ pe ṣaaju, iyẹn, l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kọkanlelogun, oṣu Keje, ọdun yii, lawọn afurasi ọdaran yii ti ji iya kan to n jẹ Patience Okafor gbe lasiko ti iya naa n gbe awọn ọmọ ẹ lọ sileewe ni nnkan bii aago mẹjọ aabọ aarọ ọjọ naa.

Gẹgẹ bii iṣe awọn afurasi ajinigbe yii, wọn tun wa awọn ọmọ iya naa gunlẹ soju ọna pẹlu ọkọ jiipu ti iya wọn fi n gbe wọn lọ sileewe, wọn si gbe Abilekọ Okafor lọ sinu igbo rere.

Ninu ifọrọwerọ ti awọn karanbaani eeyan wọnyi ṣe pẹlu akọroyin wa ni wọn ti ṣalaye bi awọn paapaa ṣe ko ṣọwọ awọn afurasi ọdaran to tun ya ogbologboo ju awọn lọ, to si jẹ pe Ọlọrun lo yọ awọn ti awọn agbebọn agbegbe Niger-Delta naa ko pa awọn sinu omi fun awọn ọọni ati ẹja nla nla inu omi jẹ.

Adewale, ẹni ọdun mọkanlelogoji, tawọn ẹlẹgbẹ ẹ tun mọ si Oro, lo ṣalaye iṣẹlẹ naa, o ni “Ọkan ninu wa to n jẹ OJ lo mu mi mọ BJ (Abọlaji).

“Eyi kọ nigba akọkọ ti awọn ọlọpaa maa mu mi. Ẹsun idigunjale ọkọ ni wọn mu mi fun ni nnkan bii ọdun mẹrin si marun-un sẹyin, ti mo si lo nnkan bii ọdun kan gbako lọgba ẹwọn ko too di pe Ọlọrun, ninu aanu Rẹ, ko mi yọ.

‘‘Emi o mọ nipa ijinigbe tẹlẹ. Awọn BJ yii naa ni wọn kọ mi. Ọrẹ mi to n jẹ OJ ninu wa lo mu mi mọ BJ. Ka maa ji eeyan yẹn ti yọ lẹmi temi, koda, mo ti búra nídìí Ogun pe mi o ni i ba wọn ṣe e mọ, gbese nla kan ta a jẹ lo jẹ ki n ba wọn pada sidii ẹ, pe ki n ṣe ẹẹkan pere yẹn lati san an.

Ki lo fa gbese? Eeyan mi kan lo pe mi ki n ba oun wa ibọn AK 47. Mo fi ọrọ yẹn lọ BJ, o ba ba mi pe ẹnikan. Ẹni yẹn lo fun wa ni nọmba foonu awọn to fẹẹ ta ibọn niluu Ughelli, nipinlẹ Delta.

“Emi pẹlu ọrẹ mi, OJ la jọ lọ, ọkọ Toyota Matrix kan ta a ya lọwọ ẹnikan la gbe lọ. Ṣugbọn nnkan ta o lero rara la ba pade ni Ughelli, nitori iya ni wọn fi ki wa kaabọ. Lẹyin ti wọn lu wa tan ni wọn gba gbogbo owo ọwọ wa ati gbogbo owo to wa ninu akanti wa”.

Njẹ ki lo de ti awọn to fẹẹ ta ibọn fun wọn ṣe lu wọn, ọkunrin ẹni ọdun mọkanlelogoji yii ṣalaye pe “ọwọ awọn agbebọn agbegbe Niger-Delta la ti fẹẹ lọọ ra ibọn, wọn lẹni to fẹẹ ra ibọn yẹn ti pẹ ju ko too fowo ẹ ranṣẹ sawọn, ati pe awọn fura si wa pe ọlọpaa ni wa, a n dọgbọn lati mu awọn ni. Bi wọn ṣe bẹrẹ si i lu wa niyẹn.

‘‘Lẹyin miliọnu kan ati ẹgbẹrun lọna igba Naira (₦1.2) ti ẹni to fẹẹ ra ibọn fi ranṣẹ si wọn, wọn gba gbogbo owo to wa lọwọ wa. Ẹgbẹrun lọna ọtalelẹgbẹta Naira, o din mẹwaa (N650,000) lowo to wa ninu akanti mi lasiko yẹn, awọn eeyan yẹn gba kaadi ti mo fi n gbowo lọwọ mi, wọn si gba gbogbo owo yẹn.

Lẹyin naa ni wọn pinnu pe nṣe lawọn maa pa wa. Wọn waa fokun di wa lọwọ atẹsẹ, wọn fẹẹ lọọ gbe wa ju sinu odo ti awọn ọọni pọ si, ki awọn ọọni le fi wa ṣe ounjẹ. Nigba ti mo ri i pe okun ti wọn fi so mi lọwọ ti dẹ diẹ ni mo sa lọ mọ wọn lọwọ.

“Mo dele, mi o le royin nnkan to ṣẹlẹ fun ẹni to ran mi nibọn. Idi ni pe bi mi o ṣe ri ibọn gbe wale, o ro pe niṣe ni mo fẹẹ lu oun ni jibiti. Ẹni yẹn si ree, eeyan kan to buru gidi gan-an ni. Owo ibọn rẹ naa ni mo n wa ti mo fi ba wọn kopa ninu iṣẹ (ijinigbe) ta a ṣe gbẹyin ti awọn ọlọpaa fi mu wa. Bẹẹ naa ni mo n wa owo ta a maa fi ra mọto ti awọn ọmọ Niger-Delta gba lọwọ wa pada.

Azeez Aleṣe Bakare to jẹ olori ikọ awọn ajinigbe yii. Ọmọ bibi ilu Agọ-Iwoye, nipinlẹ Ogun, ni ṣugbọn orile-ede Ghana lo n gbe tẹlẹ, ọdun 2022 lo ti Ghana de s’Ibadan, to si sọ eeyan jijigbe diṣẹ aṣejẹun tiẹ.

Nigba to n royin bi wọn ṣe n ṣiṣẹ laabi wọn ọhun, ọkunrin ẹni ọdun mejidinlogoji yii ṣalaye pe “emi ni mo mu imọran wa laarin awọn eeyan wa pe ki wọn jẹ ka maa ṣiṣẹ yii. Inu oṣu Kẹta, ọdun yii, naa la bẹrẹ, o si digba marun-un ọtọọtọ ta a ti ji eeyan gbe.

“Ko sẹni to kọ mi niṣẹ yii. Ṣugbọn nigbakuugba ti awọn ọlọpaa ba mu awọn ajinigbe, gbogbo ọrọ ti awọn eeyan yẹn ba sọ pata ni mo maa n fara balẹ gbọ. Ninu awọn alaye ti wọn ba ṣe nipa bi wọn ṣe ji eeyan gbe ni mo ti kọ ẹkọ nipa bi eeyan ṣe le maa ji eeyan gbe pamọ, ti mo si sọ fawọn yooku mi pe ki wọn jẹ ki awa naa maa ṣe e.

‘‘Ọrẹ mi to n jẹ J.K. ni mo pe wa lati Ijẹbu-Ode pe ko waa maa ba wa mojuto awọn to ba wa ninu igbekun wa. Mọto mi la lo lọjọ ta a kọkọ ji eeyan gbe ninu oṣu Kẹta, lọna Iperu, nipinlẹ Ogun. Ọkunrin kan la ji gbe lọjọ yẹn ta a si lọọ tọju ẹ sinu igbo kan niluu Ṣagamu.

‘‘Emi ati Dagunro la duro ti i ninu igbo laarin ọjọ mẹta to fi wa nigbekun wa. Miliọnu mẹfa Naira (N6m) la gba lọwọ awọn ẹbi ẹ. Emi ni mo maa n gbowo ju awọn yooku lọ nitori emi ni mo n ṣe eyi to pọ ju ninu iṣẹ yẹn.

‘‘Ibọn mejeeji ta a lo nigba yẹn ko ṣiṣẹ daadaa. Lẹyin iṣẹ akọkọ yẹn ni OJ ati Oro ra ibọn nla nla gidi kọọkan. Emi o mọ ibọn ọn yin, emi kan maa n gbe ibọn lọwọ lasan ni, Oro lo mọ ọn yin, to maa n yinbọn soke lati dẹruba ẹni ta a ba fẹẹ ji gbe.

‘‘Adugbo Challenge, n’Ibadan, la ti ṣiṣẹ wa ẹlẹẹkeji. Mo ti kọkọ ri ile ọkọ obinrin yẹn, mo si mọ pe eeyan kan to lowo gan-an ni wọn maa jẹ. Niṣe ni mo kọkọ lọ saduugbo yẹn lati fimu finlẹ. Bi mo ṣe maa n ṣe ka too ji eeyan gbe niyẹn lati ṣewadii nipa ẹni ta a ba fẹẹ gbe. Mo maa n dibọn bii ẹni to n wa ile laduugbo yẹn. Ile ọti kan wa nitosi ile awọn obinrin naa, nile ọti yẹn ni mo wa lọjọ kan ti ọkọ obinrin yẹn fi wa mọto kọja, awọn eeyan waa sọ pe o ṣẹṣẹ ti Amẹrika de ni.

Awọn nnkan ti mo ti mọ nipa ara Amẹrika yii lo jẹ ki n sọ fun Oro to jẹ igbakeji mi pe ọkunrin yẹn lẹni to kan ta a maa ji gbe. Ṣugbọn lọjọ ta a lọ, a ri i ti obinrin yẹn n gbe awọn ọmọ wọn lọ si sukuu, a si ri i pe eeyan to tutu lawọ daadaa ni. Ba a ṣe kuku pinnu lati ji oun naa gbe niyẹn.

Kenny lo ni ọkọ ayọkẹlẹ Lexus ta a gbe lọ. Ba a ṣe sun mọ obinrin yẹn ni mo na ibọn si i lati dẹruba a. Obinrin yẹn pẹlu ọkunrin kan bayii to ti dagba nikan la gbe sa lọ, a fi awọn ọmọ silẹ ninu mọto wọn nibẹ. Awa maraarun, emi, Oro, OJ, Kenny ati Dagunro la jọ ṣiṣẹ yẹn.

‘‘Ọna Onigaari (lọna Eko) la kọkọ n gbe wọn lọ. Nigba ta a ri awọn ọlọpaa lọọọkan la

tọọnu pada. Ba a ṣe pe ọrẹ wa kan lori foonu niyẹn pe ko ba wa ṣeto inu igbo kan ta a le tọju awọn ta a ji gbe pamọ si lagbegbe Ẹgbẹda (n’Ibadan).

“Ẹni yẹn naa lo ba wa mojuto wọn laarin asiko ti wọn lo ninu igbekun wa. Miliọnu lọna aadọta Naira (N50m) la beere, ṣugbọn miliọnu mẹẹẹdogun Naira (N15m) ni mọlẹbi wọn ri fun wa ka too fi wọn silẹ lọjọ kẹrin”.

Nigba to n ṣalaye bo ṣe yan awọn yooku rẹ jẹ lori owo yii, BJ sọ pe “gbogbo igba ti mo ba ti pin owo ni OJ maa n ba mi ja pe owo ti emi mu ti pọ ju, bẹẹ, emi ni mo n ṣe eyi to pọ ju ninu awọn iṣẹ yẹn. Idi niyẹn ti mo ṣe tọju pamọ ninu owo yẹn. Ẹẹmeji ni mo gba owo yẹn. Mo kọkọ gba miliọnu marun-un Naira, mo tọju iyẹn funra mi ko too di pe mo gba miliọnu mẹwaa Naira ti awa maraarun jọ pin”.

O ni loootọ lawọn ti fẹẹ pa iṣẹ ajinigbe ti, ṣugbọn gbese ti awọn jẹ nigba ti awọn to fẹẹ ta ibọn fawọn gba mọto lọwọ Oro ati OJ. Eyi lo mu ki ẹni to bẹ awọn nibọn binu gba mọto ayọkẹlẹ oun rọpo owo ibọn rẹ, ati pe owo ti awọn yoo fi san gbese owo ibọn ọhun lawọn n wa ti awọn tun ṣe pinnu lati tun ji ẹni kan gbe lẹẹkan si i.

Njẹ bawo lọwọ awọn agbofinro se tẹ ẹ, ọga awọn afurasi ajinigbe yii ṣalaye pe “mo fẹẹ ṣe faaji ninu ẹgbẹrun lọna igba Naira (N200,000) to ṣẹku si mi lọwọ. Mo sọ fun iyawo mi pe mo fẹẹ tirafu, mo waa pe ọrẹbinrin mi pe ko jẹ ka jọ lọọ gbadun ara wa mọju nileetura.

Inu yara ta a wa ninu ileetura ni mo ti n gbọ gba! Gba! Gba! lara ilẹkun. Ọkan ninu awọn oṣiṣẹ otẹẹli yẹn ni mo pe e, mo ba sọ fun ọrẹbinrin mi pe ko lọọ ṣilẹkun laimọ pe awọn ọlọpaa ni. Bi awọn ọlọpaa ṣe wọle tọ mi wa ni mo ti mọ pe mo ti rogo.

“Nigba ti ọwọ awọn ọlọpaa tẹ mi yii ni mo waa mọ pe iwa ọdaran ko pe, o maa n ba ni lorukọ jẹ ni. Emi ti ba orukọ idile wa jẹ, nitori mo gbọ pe bi mama mi ṣe gbọ iroyin pe awọn ọlọpaa ti mu bayii ni wọn daku lọ gbọnrangandan. Emi paapaa ti sunkun, sunkun, ninu ahamọ awọn ọlọpaa ti mo wa yii, omi ti gbẹ loju mi patapata.”

Inu ahamọ awọn ọlọpaa ọhun naa ni BJ ati Oro ṣi wa titi ta a fi pari akojọ iroyin yii nigba ti iwadii ṣi n tẹsiwaju lori oriṣiiriṣii ẹsun ijinigbe ti wọn fi kan awọn afurasi ọdaran yii.

Leave a Reply