Gbogbo ileepo ti ko ba ta bẹntiroolu faraalu ni Kwara yoo foju wina ofin-NSCDC

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Nitori ki irọrun le de ba awọn araalu, ẹsọ alaabo ṣifu difẹnsi, ẹka ti ipinlẹ Kwara, ti sọ pe awọn yoo maa kaakiri awọn ileepo nipinlẹ naa, eyikeyii to ba tilẹkun mọ epo lai ta a ninu wọn yoo foju wina ofin ijọba.

Ọjọruu, Wẹsidee, ọṣẹ yii, ni adari ajọ naa nipinlẹ ọhun, Ọgbẹni Makinde Iskil Ayinla, fọrọ naa lede fawọn oniroyin niluu Ilọrin. O ni awọn woye pe ọpọ awọn ileepo ni wọn n da kun iṣoro ọwọngogo epo to fẹẹ gbilẹ latari pe wọn n tilẹkun mọ epo wọn lai ta a, to si jẹ pe inira lo jẹ fun araalu.

Makinde tẹsiwaju pe ni bayii, ajọ naa yoo maa yi gbogbo ilu ka, ti yoo si maa ya awọn ileepo, eyikeyii ninu wọn to ba de epo mọle yoo fimu kata ofin. Bakan naa lo sọ pe awọn ileepo kan tun wa ti wọn fowo kun owo-epo wọn yatọ si iye tijọba ni ki wọn maa ta a. O ni gbogbo wọn pata ni wọn yoo koju ijiya to tọ tọwọ ba tẹ wọn.

Agbẹnusọ ajọ naa nipinlẹ Kwara, Ọgbẹni Babawale Zaid Afolabi, sọ pe iroyin de si etiigbọ ajọ NSCDC pe ṣe ni awọn ileepo kan ni epo, ṣugbọn ti wọn kọ lati ta a, nigba ti awọn miiran fi kun iye ti wọn n ta jala epo wọn. O tẹsiwaju pe gbogbo awọn alaṣẹ alagbata epo nipinlẹ Kwara ni wọn yoo maa tọwọ bọwe adehun pe wọn o ni i ta epo ju iye ti ijọba fọwọ si ki wọn o maa ta jala epo kan lọ.Ni igunlẹ ọrọ ti ẹ, o ni ajọ naa ti ṣe abẹwo si awọn ileepo to n lọ bii aadọta niluu Ilọrin ati awọn ilu to fẹgbẹkẹgbẹ pẹlu rẹ bii Ọffa, Alapa, Bode Saadu, Omu-Aran, ati bẹẹ bẹẹ lọ, kawọn le mọ bi nnkan ṣe n lọ lori ọwọngogo epo.

Leave a Reply