Ọlawale Ajao, Ibadan
Gbogbo awọn ondupo to dije lorukọ ẹgbẹ oṣelu People’s Democratic Party, PDP, ninu idibo ijọba ibilẹ to waye lojo Abamẹta, Satide, to kọja yii, ni wọn jawe olubori sipo kansilọ ati ipo alaga kansu kaakiri ijọba ibilẹ mẹtẹẹtalelọgbọn (33) to wa nipinlẹ Ọyọ.
Wọn ko ti i dibo ijọba ibilẹ Ido, Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii, ni Aarẹ Isiaka Abiọla Ọlagunju ti i ṣe alaga ajọ eleto idibo ipinlẹ yii (Oyo State Independent Electoral Commission, OYSIEC) sun atundi ibo ijọba ibilẹ Ido si bayii. Eyi waye nitori bi ajọ eleto idibo ṣe gbagbe lati fi orukọ ẹgbẹ oṣelu ZLP sinu iwe idibo naa.
Bakan naa ni wọn yoo tun idibo kansilọ di ni Wọọdu karun-un, niluu Eruwa, nijọba ibilẹ Ila-Oorun Ibarapa.
Ṣaaju lalamoojuto eto idibo ijọba ibilẹ naa, Ọgbẹni Thomson Iṣọla, ti royin iṣẹlẹ to mu ki wọn fagile idibo kansilọ naa.
O ni “A bẹrẹ idibo daadaa, ohun gbogbo si n lọ deede gẹgẹ bo ṣe yẹ ki eto idibo gidi ṣe lọ. Nigba to di ọsan la gbọ pe awọn tọọgi ti da eto idibo ru nibudo idibo kẹta, ni wọọdu karun-un. A ṣewadii, a si gbọ pe ootọ ni, wọn ti ba gbogbo ibudo idibo wọọdu agbegbe Eruwa Tuntun, niluu Eruwa jẹ.
“Awọn tọọgi gbe iwe idibo sa lọ nibudo idibo keje, ni Wọọdu karun-un yìí kan naa. A si pinnu lati fagi le awọn ibo wọọdu yẹn.”
Eyi ni abajade esi idibo naa pẹlu iye ibo ti ẹgbẹ oṣelu PDP ni ninu idibo alaga ijọba ibilẹ kọọkan ati orukọ awọn alaga tuntun naa ti wọn yoo tukọ ijọba ibilẹ kaluku wọn fun odidi ọdun mẹrin si asiko yii.
ITẸSIWAJU
PDP:15,875
Ojo Bọlaji
ISẸYIN
PDP: 39,275.
Ọnarebu Oṣuọlale
KAJỌLA
PDP: 21,933.
Afọlabi A. Adebayọ
IWAJỌWA
PDP 15,614
Oyinloye Jẹlili Adebare
ATISBO
PDP: 20,871.
Adeagbo Fasasi Ademọla
ILA-OORUN ṢAKI
PDP: 16,064.
Adediran A. Mosunmade
IWỌ-OORUN ṢAKI
PDP: 29,797
Muideen Sarafadeen
OORELOPE
PDP: 8580. Raheem Akeem Adepọju
IRẸPỌ
PDP: 21,677
Sulemana Lateef Adediran
ỌLỌRUNṢOGO
PDP: 10692
Akanni Juliana Olúwakẹ́mi
ARIWA OGBOMỌṢỌ (OGBOMỌṢỌ NORTH)
PDP: 23,008
Arẹmu Kabir Ayọade
GUUSU OGBOMỌṢỌ (OGBOMỌṢỌ SOUTH)
PDP: 23, 506
Oyeniyi Thimothy
OGO OLUWA
PDP: 14873
Ojo Oluwaṣeun Adesoye
ORIIRE
PDP: 23,016.
Alabi Ọlatẹju Michael
SURULERE
PDP: 22526
Adegbitẹ Isiah Alaba
AARIN-GBUNGBUN IBARAPA (IBRP CENTRAL)
PDP: 9,987.
Ọnarebu Oloyede
ARIWA IBARAPA (IBARAPA NORTH)
PDP: 20,222
Lawal Azeez Adewale
AFIJIO
PDP: 15,158
Sunday Akindele Ojo
ATIBA
PDP: 14,690
Ọnarebu Mojisọla Kafila Ọlakojọ
IWỌ-OORUN ỌYỌ (ỌYỌ WEST)
PDP: 16,888
Salami Babatunde Akeem
ILA-OORUN ỌYỌ (OYO EAST)
PDP: 17141
Arowoṣaye Saheed Adeyẹmi
ILA-OORUN ARIWA IBADAN IB. NORTH EAST
PDP: 19,408
Akintayọ Ibrahim Akinṣọla
AKINYẸLE
PDP: 38492
Jimoh Taoheed Adedigba
OLUYỌLE
PDP: 11,224
Settle Ọlaide Popoọla
LAGELU
PDP: 34,704
Gbadamọsi Kazeem Adeyẹmi
IWỌ-OORUN ARIWA (IBADAN N/W)
PDP: 18,298
Adepọju R.O.
ẸGBẸDA
PDP: 28,553
Sanda Sikiru Oyedele
IWỌ-OORUN GUUSU IBADAN (IBADAN SW)
PDP: 29,182
Kẹhinde Adeyẹmi Akande
ỌNA-ARA
PDP: 22,544
Sanusi Musibau Adeṣina
ARIWA IBADAN IB. NORTH
PDP. 37,135
YUSUF S. O.
ILA-OORUN ARIWA IBADAN (IB. SOUTH EAST)
PDP: 18,027
Alawode Oluwọle Emmanuel
PDP: 12,138
Ọbalọwọ O.A.
Pẹlu bi ẹgbẹ oṣelu yooku ṣe n mura silẹ de atundi ibido ijọba ibilẹ Ido ati idibo kansilọ wọọdi karun-un nijọba ibilẹ Ila-Oorun Ibarapa, ara ija ti ẹgbẹ oṣelu APC yoo ja ni kootu ni wọn n mu nitori bi idibo ọhun ṣe ku ọjọ bii mẹta ni wọn ti gba kootu lọ, wọn ni kile-ẹjọ paṣẹ fun ijọba Gomina Makinde ti ipinlẹ Ọyọ lati ma ṣe ṣeto idibo naa nitori eto ọhun ko ni i yatọ si ifowo-ijọba-ṣofo lasan.