Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Nibi eto naa to waye lori papa iṣere ilu Oṣogbo lọjọ Abamẹta, Satide, ni awọn aṣoju ẹgbẹ naa ti wọn din ni ẹgbẹrun meji kaakiri ijọba ibilẹ kora wọn jọ fun eto naa.
Ṣaaju ni alaga igbimọ to ṣe kokaari idibo ọhun lati Abuja, Ọnọrebu Ẹlẹgbẹlẹyẹ, ti kede pe eto idibo naa yoo waye lai ni eru kankan ninu, o ni gbogbo ọmọ ẹgbẹ ni wọn gbọdọ fọwọ si ẹnikẹni ti wọn ba yan.
Lẹyin eyi ni awọn aṣoju ẹgbẹ lati ijọba ibilẹ kọọkan n jade sita lati nawọ soke lori awọn oloye ti wọn fẹ ki wọn maa dari wọn fun saa yii.
Lasiko yii ni wọn yan Ọmọọba Gboyega Famọọdun gẹgẹ bii alaga wọn fun saa keji, wọn yan Alhaji Tajudeen Lawal gẹgẹ bii igbakeji alaga, Ọgbẹni Alao Kamar Ọlabisi, si di akọwe ẹgbẹ.
Ọnarebu Fẹmi Kujẹnbọla ni wọn mu gẹgẹ bii akọwe, Alhaja Kudirat Fakokunde, ni adari awọn obinrin, Ọgbẹni Akinwẹmimọ Ibrahim Adegoke, si di adari awọn ọdọ, ati awọn mejidinlọgbọn miran.
Ninu ọrọ idupẹ rẹ, Famọdun dupẹ lọwọ Gomina Oyetọla ati awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC nipinlẹ Ọṣun fun igbagbọ ti wọn ni ninu rẹ to jẹ ki wọn tun un yan sipo.
O waa ke si gbogbo awọn oloye tuntun lati lo gbogbo agbara ati ipa to wa nikaawọ wọn fun atilẹyin iṣejọba Gomina Oyetọla, o ṣalaye pe ohun kan ṣoṣo to gbọdọ jẹ wọn logun bayii ni bi ẹgbẹ APC yoo ṣe rọwọ mu ninu idibo gomina lọdun to n bọ.
Bakan naa ni Gomina Oyetọla rọ awọn ọmọ ẹgbẹ lati mu ihinrere ifẹ ati iṣọkan lọkun-un-kundun, o ni loootọ ni ikunsinu diẹdiẹ wa ninu ẹgbẹ naa, eleyii to ni ki i ṣe tuntun, ṣugbọn o ni arẹmaja kan ko si.
Oyetọla sọ pe oniruuru iṣẹ rere to n lọ lọwọ l’Ọṣun nipasẹ ijọba APC ko gbọdọ duro rara, o ni ki onikaluuku wa ọna lati fa oju awọn ti inu n bi mọra, ki wọn si mọ pe idibo to n bọ ṣe pataki pupọ.