Taiwo bimọ fun Kẹhinde ẹ lẹẹmẹji, o loun maa n gbadun ‘kinni’ ekeji oun

Faith Adebọla

Ọrọ buruku toun tẹrin lọrọ naa jọ, palapala ilu apala ni, ṣugbọn eegun to ba ti jade ti kuro ni ‘aiwo o,’ iyẹn ni ija nla to waye laarin awọn ibeji ẹni ọdun mọkandinlọgbọn yii, Ọgbẹni Amos Kunde toun jẹ Taye, ati Kẹhinde ẹ, Juliana Kunde. Ọmọ meji lanti lanti ni Kẹhinde yii ti bi fun Taiwo ẹ to fun un loyun, ija nla to ṣẹlẹ laarin wọn lo mu ki akara iṣẹkuṣe yii tu s’epo.

Ọmọ bibi ijọba ibilẹ Guma, nipinlẹ Nassarawa, ni wọn, ṣugbọn agbegbe ijọba ibilẹ Awe, lawọn atawọn obi wọn n gbe lati kekere, iṣẹ oko ni wọn si n ṣe.

Ọdun 2013 niṣẹlẹ aburu kan ṣẹlẹ, nigba tawọn Fulani darandaran ṣakọlu sawọn eeyan agbegbe naa ninu oko wọn, wọn pa ọpọ eeyan, awọn obi Taye-Kẹyin yii si wa lara awọn to doloogbe, koda ori lo ko awọn ibeji naa yọ tori awọn ẹgbọn wọn naa wa lara awọn to ku pẹlu, ni wọn ba dọmọ orukan latigba naa.

Iṣẹlẹ yii lo mu awọn mejeeji sa lọ si abule kan ti wọn n pe ni Doku, nijọba ibilẹ Doma, nibi ti ipinlẹ Nasarawa ati Benue ti paala, iṣẹ agbẹ ni wọn fi n gbọ bukaata ara wọn nibẹ.

Juliana jẹwọ fakọroyin The Nation pe loootọ ni oun ti ni ọrẹkunrin kan nigba toun ṣi wa nileewe pamari, ọrẹkunrin naa lo gba ibale oun, ṣugbọn iṣẹlẹ ojiji to mu awọn obi ati mọlẹbi awọn lọ lo ṣokunfa ajọṣepọ to di wahala sawọn lọrun yii.

O ni oun ati ekeji oun jọ n ṣiṣẹ oko ni, ile kan naa lawọn n sun, ṣugbọn yara ọtọọtọ ni, awọn o si lẹlomi-in tawọn foju jọ ju awọn meji yii naa lọ.

“Lọjọ kan, bi a ṣe n hu iṣu lọwọ, niṣe ni ṣokoto ẹ (Taiwo) ṣadeede fa ya labẹ bo ṣe ni koun jokoo, mo si ri ‘kinni’ ẹ, ni mo ba bu sẹrin-in, o mọ pe tori nnkan ti mo ri ni mo ṣe rẹrin-in, o bi mi pe ki lo n pa mi lẹrin-in, mo ni ‘kinni ẹ yii le ṣe obinrin to ba gba mu leṣe o,’ lawa mejeeji si jọ rẹrin-in.

Lalẹ ọjọ yẹn nigba ta a dele, mo n dana lọwọ nile idana wa, oun naa si wa sibẹ, o waa wo o boya awọn adiẹ to n sin ti wọ̀, bo ṣe n tan tọọṣi ọwọ ẹ kiri, o tanna si mi labẹ lojiji, emi o si wọ pata, loun naa ba bu sẹrin-in, ṣugbọn mo sare para mọ. Nigba to di oru, lo ba waa ba mi ni yara ti mo n sun, o loun nilo bileedi, mo fẹẹ ba wa a, bo ṣe di pe a jọ dira wa mu niyẹn, o ni ki n jẹ ka dan ibalopọ wo, mo si gba, ka too mọ ohun to n ṣẹlẹ, o ba mi lo pọ loru ọjọ yẹn.

Latigba naa lemi atiẹ ti jọ n laṣepọ, o si da bii pe a gbadun ẹ, ṣugbọn a o jẹ kẹnikẹni mọ, a ṣe e laṣiiri laarin ara wa ni. Ibeji lawọn eeyan maa n pe wa, awọn mi-in si maa n ro pe tẹgbọn-taburo ni wa, awa naa o si jẹ ki wọn mọ nnkan to ṣẹlẹ rara.

Lati ọdun 2015 yẹn, ọmọ meji ni mo ti bi fun un. Lẹyin ti mo bi alakọọkọ, awọn eeyan ro pe mo gbe oyun naa wa lati ibi ti a ti n bọ ni, ati pe boya ọkọ mi ti ku ninu iṣẹlẹ to le wa jade, ṣugbọn nigba ti oyun ọmọ keji tun ṣẹlẹ, a ko kuro niluu ti a n gbe lọ siluu mi-in, ilu Tse Ngba la ko lọ, awọn eeyan ibẹ ko si mọ pe ibeji ni wa rara, tọka-taya ni wọn n pe wa, ti mo fi bimọ keji, iṣẹ agbẹ naa la si n ṣe, Ọlọrun si n fibukun sori iṣẹ wa.

Ko sọ fun mi poun maa fẹyawo mi-in o, niṣe lo sọ fun mi pe a maa ran awọn ọmọ wa lọ sileewe nigba tawa mejeeji ko ti lanfaani lati kawe, ka le sinmi ṣiṣi kiri bii ẹyẹ, afi bo ṣe tun waa sọ fun mi pe oun fẹẹ fẹyawo tuntun, mo ni bawo lo ṣe fẹẹ ṣe ọrọ temi pẹlu awọn ọmọ si, tori mo mọ pe ko siyawo to le fẹ to maa fara mọ ohun to ṣẹlẹ nigbesi aye wa, mi o si fẹ ẹni to maa waa da ẹmi awọn ọmọ mi legbodo, ṣugbọn katikati lo n sọ, o lawọn ọmọ maa yanju ọrọ ara wọn to ba ya, iyẹn ni mo fi yari mọ ọn lọwọ, mi o si ni i gba fun un.”

Juliana tun jẹwọ pe “inu mi o tiẹ dun pe ẹlomi-in maa waa gbadun Taiwo mi, tori mo laiki bo ṣe maa n ba mi ṣere ifẹ, ko sigba to ṣe ‘kinni’ pẹlu mi ti ki i tẹ mi lọrun daadaa, o digba to ba rẹ mi tẹnutẹnu ko too fi mi silẹ, mo maa sun oorun asunwọra ni. Mi o tiẹ ki i ranti mọ pe ọmọ iya kan naa ni wa, mi o ki i wo ara mi bii ibeji ẹ mọ rara, o mọ ere i ṣe gidi ni.”

Nigba ti Amos n ṣalaye bọrọ ṣe jẹ ni tiẹ, o ni Kẹhinde oun lo fa ọran yii, o loun lo tan oun si i, oun si ti ko wọ ọ tan toun o mọ ọgbọn toun fẹẹ da si i bayii, o ni bo ṣe maa n ṣira silẹ toun pẹlu ẹ ba ti n ṣiṣẹ ninu oko lo ṣakoba foun.

O loun kabaamọ nnkan to ṣẹlẹ yii tori nnkan ma-jẹ-a-gbọ ni, o ni alaalẹ lo maa n ṣira silẹ ni kiṣinni toun ba n tọju awọn adiẹ oun, o loun kọkọ ro pe ko mọ-ọn-mọ, tabi pe o ṣeeṣi ni, ṣugbọn nigba to ya, oun ri i pe o fẹ nnkan kan ni, gẹgẹ bii ọkunrin, oun si fun un ni nnkan to fẹ.

O ni loootọ lọrọ ti Kẹhinde sọ, o ni boun ṣe fẹẹ fẹyawo mi-in ki i ṣe tori ati ja a ju silẹ, o ni oun nilo ẹni to maa ran oun lọwọ lẹnu iṣẹ oko ni, nigba ti ‘ibeji-di’yawo’ oun yii si ṣi n tọmọ lọwọ.

Mo tun sọ fun un pe oun naa ṣi le lọkọ tuntun, mo si gba lati mojuto awọn ọmọ wa to ba ṣẹlẹ pe o lọkọ tuntun, ṣugbọn ko fẹẹ gba, o loun o ni i jẹ ki n fẹyawo mi-in, bẹẹ loun o ni i fi mi silẹ, iku lo n gba’ṣọ lara ewurẹ lọrọ emi atoun. Iku ojiji awọn obi wa lo fa jọgọdi yii, aye mi si ti su mi pẹlu, mi o layọ rara.”

Ohun ta a gbọ ni pe awo ọrọ yii ti lu si awọn agbaagba ilu ti wọn n gbe naa lọwọ, wọn si ti n ba wọn wa iyanju si i, wọn ni nnkan eewọ ni wọn ṣe, o le fa akufa fawọn mejeeji atawọn ọmọ wọn, tori naa, wọn gbọdọ tete gbe igbesẹ lori ẹ.

Leave a Reply