Gomina Abdulrazak gbe igbimọ ti yoo yanju aawọ Ọffa ati Ẹrinle kalẹ  

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Ọjọ Aje, Monde, ọṣẹ yii, ni Gomina ipinlẹ Kwara, Abdurahman Abdulrazaq, ṣe ifilọlẹ awọn igbimọ kan ti wọn yoo wa ojutuu si aawọ to n waye laarin ilu Ọffa ati Ẹrinle lati ọjọ pipẹ, ti alaafia yoo si jọba laaarin awọn ilu mejeeji ọhun.

Ninu atẹjade kan ti Akọwe iroyin Gomina, Ọgbẹni Rafiu Ajakaye, fi sita lọjọ Aje, Monde, ọṣẹ yii, lo ti fidi ifilọlẹ awọn igbimọ naa mulẹ. Awọn igbimọ ọhun ni gomina tẹlẹ, Cornelius Adebayọ, to jẹ alaga wọn, awọn eeyan nla nla ti wọn jẹ amofin ati awọn to tun mọ itan, to fi mọ awọn ọmọwe, ni wọn wa ninu igbimọ naa. Lara wọn ni : Adajọ Saidu Salihu; Alhaji LAK Jimoh; Oloye Titus Ashaolu; Sẹnetọ Simeon Ajibọla; Alhaji Abubakar Ndakene; Sẹnetọ Mohammed Ahmed; Amofin Sabitiyu Kikẹlọmọ Grillo; ati Ọjọgbọn Hassan Saliu (Akọwe).

AbdulRazaq rọ awọn igbimọ naa lati sa gbogbo ipa wọn, ki wọn si wa ọna abayọ lati bomi pana aawọ to ti n mu ki awọn ilu mejeeji padanu ọpọ ẹmi ati dukia lati ọjọ pipẹ.

O tẹsiwaju pe ija ti awọn ilu mejeeji ja kẹyin ninu oṣu kẹta, ọdun yii, lo ti mu ifasẹyin ba eto ọrọ aje agbegbe naa, to si yẹ ki ijọba tete gbe igbesẹ lori aawọ naa. Gomina ki awọn igbimọ naa ku oriire fun anfaani ti wọn ri lati ṣiṣẹ sin ilẹ baba wọn, bakan naa lo ni ijọba ko ṣetan lati ṣegbe lẹyin ilu kankan bọya Ọffa tabi Ẹrinle.

Ifilọlẹ ọhun lo waye nile ijọba ipinlẹ Kwara, to wa ni ilu Ilọrin, ti i ṣe olu ipinlẹ Kwara. Olori oṣiṣẹ si Aarẹ Muhammed Buhari, Ọjọgbọn Ibrahim Gambari Agboọla, naa wa lara awọn to peju sibi ifilọlẹ ọhun.

 

Leave a Reply