Gomina Babajide Sanwo-Olu di alaga ẹgbẹ apapọ awọn gomina ilẹ Yoruba

Adewale Adeoye

Ni bayii, apapọ ẹgbẹ awọn gomina ipinlẹ Yoruba ‘South-West Governors Forum’ ti lawọn ko fara mọ ipolongo kan tawọn alakatakiti kan n ṣe pe ki ẹya Yoruba da duro, eyi ti wọn n pe ni Yoruba Nation. Ọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kẹwaa, oṣu Kẹfa, ọdun 2024 yii, ni apapọ ẹgbẹ ọhun bẹnu atẹ lu igbesẹ ati erongba awọn eeyan ọhun ti wọn n ṣepolongo fun idasilẹ orileede Yoruba Nation bayii. Paapaa ju lọ, bi awọn kan ṣe tun fẹẹ fipa gbajọba ni sẹkiteraiti ipinlẹ Ọyọ, loṣu to kọja yii.

ALAROYE gbọ pe lẹyin ipade pataki kan to waye lọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii, laarin gbogbo awọn gomina ilẹ Yoruba, to waye ni Alausa, niluu Ikeja, ipinlẹ Eko, ni wọn ti sọ pe ko gbọdọ s’ohun to n jẹ Yoruba Nation lorileede yii nitori pe, ọkan ṣoṣo ni gbogbo wa pata lorileede yii, ẹya Yoruba ko si le pin kuro lara orileede Naijiria rara. Ipade ọhun to gba awọn gomina naa to wakati mẹrin ni wọn tun lo akoko naa lati fi kẹdun Oloogbe Rotimi Akeredolu to jẹ olori ẹgbẹ naa tẹlẹ ko too ku.

Bakan naa ni wọn tun gboṣuba nla fun Gomina ipinlẹ Ondo, Ọgbẹni Lucky Ayedetiwa, bo ṣe ri tikẹẹti ẹgbẹ APC to fi fẹẹ dupo gomina ipinlẹ naa gba lọwọ ẹgbẹ.

Lara awọn gomina ilẹ Yoruba ti wọn peju-pesẹ sibi ipade pataki ọhun ni: Gomina ipinlẹ Eko, Babajide Sanwo-Olu, Gomina ipinlẹ, Ondo, Lucky Ayedetiwa, Gomina ipinlẹ Ọyọ, Ṣeyi Makinde, Gomina ipinlẹ Ọṣun, Sẹnetọ Ademọla Adeleke Jackson, Gomina ipinlẹ Ogun, Ọmọọba Dapọ Abiọdun ati Gomina ipinlẹ Ekiti, Ọgbẹni Abiọdun Oyebanji.

 

Leave a Reply