Faith Adebọla
Ko ti i pe wakati mẹrinlelogun ti Aṣiwaju Bọla Ahmed Tinubu ṣabẹwo si Aarẹ Muhammadu Buhari lati fi erongba rẹ to o leti pe oun maa jade dupo aarẹ lọdun 2023, ti Gomina ipinlẹ Ebonyi, David Umahi, naa ti ṣabẹwo tiẹ, oun naa ti lọọ sọ fun Buhari pe oun maa dupo aarẹ ninu eto idibo gbogbogboo to n bọ. Abẹ asia All Progressive Congress (APC) loun naa si ti maa jade.
Umahi ṣalaye fawọn oniroyin lẹyin ipade toun ati Buhari tilẹkun mọri ṣe nile ijọba, l’Abuja, lọjọ Iṣẹgun, Tusidee ọsẹ yii, pe igbesẹ naa pọn dandan lati jẹ ki Aarẹ mọ ipinnu oun.
Gomina naa sọ pe Ọlọrun nikan lo mọ ẹni ti ipo naa yoo ja mọ lọwọ, ṣugbọn ko sohun to buru lati ja fun un, paapaa beeyan ba ni ero rere lọkan bii toun.
“Idije ni, eeyan kan ṣoṣo ki i da nikan dije, emi o si wo aago alaago ṣiṣẹ, mo ni ero rere lati tun orileede yii ṣe, mo si gbagbọ pe mo maa ni anfaani lati ṣe e, tori awọn eeyan ti wọn ti ri iṣẹ ribiribi ti mo ṣe nipinlẹ Ebonyi lo bẹ mi lati jade fun ipo aarẹ.
“Bi ẹgbẹ APC ba fi aaye silẹ ki kaluku dan agbara ẹ wo, mo gbagbọ pe ma a jawe olubori lati ṣoju ẹgbẹ naa ninu eto idibo to n bọ.
“Ti mo ba si di aarẹ, ma a fi tọkan tara ṣiṣẹ fun orileede yii gẹgẹ bi mo ṣe ṣe nipinlẹ Ebonyi, gẹgẹ bii gomina. Iṣẹ olori orileede ki i ṣe yọbọkẹ, iṣẹ teeyan gbọdọ ṣe bii okoowo gidi ni, ki awọn ọmọ orileede yii si janfaani ẹ.”
Bakan naa ni Umahi loun ti ba Aarẹ Buhari sọrọ lori ọna to daa ju lati fopin si wahala eto aabo to polukurumuṣu lasiko yii, o si loun ti fi da aarẹ loju pe oun lagbara ati ọgbọn lati mu Naijiria goke agba.