Gomina Kwara ṣedaro Balogun Alanamu to jade laye

Ibrahim Alagunmu, Ilorin

Gomina ipinlẹ Kwara, Abdulrahman Abdulrasaq, ti kẹdun iku ọkan lara awọn Balogun ilu Ilọrin, Balogun Alanamu, Alhaji Abubakar Akanbi Jos, to dagbere faye Lowurọ kutu ọjọ Ẹti, Furaidee, ọṣẹ yii, lẹni ọdun mẹtadinlọgọrun-un.

Ninu atẹjade kan ti Akọwe iroyin gomina, Ọgbẹni Rafiu Ajakaye, fi síta to tẹ ALAROYE lọwọ, ni gomina ti sọ pe adanu n la ni iku oloogbe naa jẹ fun Ilọrin ati ipinlẹ Kwara lapapọ. O juwe Abubakar gẹgẹ bii olotitọ, oniwa irẹlẹ, to si n fi tọkan tara selu, ko too di pe Ọba Allah pe e sọdọ.

Abdulrahman tun kẹdun pẹlu Emir ilu Ilọrin, Dr Ibrahim Zulu Gambari, gbogbo ọmọ ẹgbẹ idagbasoke ilu Ilọrin (IEDPU) ati mọlẹbi oloogbe.

O waa gbadura pe ki Ọlọrun fi oloogbe si Alijanna onidẹra, ko si rọ gbogbo ẹbi loju.

Aarọ kutukutu ọjọ Ẹti, ọsẹ yii, ni wọn kede iku Balogun Alanamu ni ilu Ilọrin ipinlẹ Kwara, Alhaji Abubakar Akanbi Jos.

Abubakar ni Balogun kọkanla fun Alanamu ilu Ilọrin, ninu gbogbo awọn Balogun mẹrẹẹrin to di origun mẹrẹẹrin Ilọrin mu, Balogun Gambari ni Balogun agba, nigba ti Balogun Alanamu wa ni ipo keji, lẹyin naa ni Balogun Ajikobi ati Balogun Fulani.

 

Leave a Reply