Stephen Ajagbe, Ilorin
Ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii ni Gomina Abdulrahman Abdulrazaq ṣebura fawọn kọmiṣanna mẹwaa to ṣẹṣẹ yan ati oludamọran pataki kan. O si gba wọn niyanju lati mu iṣẹ wọn lọkun-unkundun, ki wọn fi apẹẹrẹ rere lelẹ, ki wọn si fọwọsowọpọ pẹlu ijọba oun.
Awọn kọmiṣanna ọhun ati ipo wọn ni; Ọgbẹni Senior Ibrahim Suleiman (Eto ẹkọ ileewe giga); Arinọla Fatimọh Lawal (Eto Idokoowo); Aliyu Kora Sabo (Ohun amuṣagbara); Aliyu Mohammed Saifudeen (Ijọba ibilẹ ati oye jijẹ); Suleiman Rotimi Iliasu (Iṣẹ-ode ati irina ọkọ); Mariam Ahmed Hassana (Akanṣe iṣẹ); Raji Razaq (Eto ilera).
Awọn to ku ni, Wahab Fẹmi Agbaje (Omi); Rẹmilẹkun Oluwatoobi Banigbe (Eto ayika); ati Deborah Arẹmu (Eto obinrin ati idagbasoke ilu).
Bakan naa, Gomina tun bura fun Mallam Attahiru Ibrahim gẹgẹ bii oludamọran pataki lori ọrọ awọn ọdọ ati ere idaraya.
Gomina gba wọn niyanju lati ri ara wọn gẹgẹ bii ẹni to waa sin araalu, o ni ki wọn fi ti araalu ṣaaju ohun gbogbo ti wọn ba n ṣe.
O ni ki wọn mọ daju pe awọn eeyan yoo bẹnu atẹ lu wọn, ṣugbọn ki wọn wa ọna lati maa fi ara da a, ki wọn si ṣe ohun to ba tọ.
Akọwe ijọba, Ọjọgbọn Mamman Saba Jibril, rọ awọn kọmiṣanna tuntun naa lati ri iyansipo wọn gẹgẹ bii anfaani lati sin araalu, ki wọn ma ja ijọba ati araalu kulẹ.
Kọmiṣanna ijọba ibilẹ ati oye jijẹ, Aliyu Saifudeen, to gbẹnu sọ fawọn ẹgbẹ rẹ ṣeleri lati ti ijọba ati eto daradara ti wọn ti bẹrẹ lẹyin. O ni awọn ko ni i ja ijọba, araalu ati ara awọn kulẹ lẹnu iṣẹ tuntun naa.