Wọn pa obinrin agbẹ kan at’ọmọ rẹ sinu oko ni Mọdakẹkẹ

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Bi ki i ba ṣe ti awọn agbaagba atawọn agbofinro ti wọn tete pẹtu sọkan awọn ọdọ kan niluu Mọdakẹkẹ lọsan-an ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii, ọrọ iba ti di iṣu-ata-yan-an-yan-an.

Awọn kan ti ko ti i ṣeni to le sọ pato ibi ti wọn ti wa lo ya wọ abule Alapata to wa nitosi Ọyẹrẹ, ti wọn si pa obinrin agbẹ kan ati ọmọkunrin rẹ ti wọn n pe ni Rueben.

Ọmọ bibi ilu Mọdakẹkẹ ni wọn pe obinrin naa, agbegbe Oke-Odo ni wọn si sọ pe o n gbe, ṣugbọn abule Alapata lo ti maa n ṣowo obi ati koko, ti aje si bu si i lọwọ daadaa.

Bi iroyin ajalu buruku naa ṣe kan de inu ilu Mọdakẹkẹ lawọn ọdọ ti lọ si abule naa, ti wọn si lọọ gbe oku awọn mejeeji. Aafin Ogunṣua ni wọn kọkọ lọ ni Ita-mẹrin, ko too di pe wọn gbe wọn lọ si agọ ọlọpaa to wa ni Oke-Otubu.

Pẹlu ọpọlọpọ ọkada la gbọ pe awọn ọdọ tinu n bi naa fi n wọ tẹle oku naa ka, ti onikaluku si n sọ oriṣiiriṣii ohun ti wọn ro pe o le fa sababi iṣẹlẹ iku ojiji naa.

Kia ni ibẹrubojo ti mu awọn eeyan ninu ilu, ti wọn si n sa kijokijo kaakiri pe ki ọrọ naa ma yọri si wahala nla. Bakan naa lawọn agbaagba n pe awọn ọdọ naa jọ, ti wọn si n rọ wọn lati fi ṣuuru tuṣu desalẹ ikoko iṣẹlẹ naa.

Alukoro fun ẹgbẹ idagbasoke ilu Mọdakẹkẹ, Venerabu Debọ Babalọla sọ fawọn oniroyin pe loootọ niṣẹlẹ naa, ṣugbọn ko ti i si ẹni to mọ ohun to ṣokunfa rẹ.

Bakan naa ni Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa l’Ọṣun, SP Yẹmisi Ọpalọla, fidi rẹ mulẹ, o ni DPO agbegbe Ifẹ ti lọ sọdọ DPO ti ilu Mọdakẹkẹ, wọn si ti pe olori ọdọ ilu Mọdakẹkẹ sipade lati le pẹtu sawọn ọdọ tinu n bi ọhun ninu.

Leave a Reply