Gomina Rotimi Akeredolu ti buwọ lu igbega awọn ọba alade kan kaakiri ipinlẹ Ondo.

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Gomina Rotimi Akeredolu ti buwọ lu igbega awọn ọba alade kan kaakiri ipinlẹ Ondo.
Ipele bii mẹrin (eyi to bẹrẹ lati ipele A B C ati D) ni wọn pin awọn ọba alade ipinlẹ Ondo si tẹlẹ ki Akeredolu too bẹrẹ iṣakoso gẹgẹ bii gomina.
Ikede yii lo waye lati ẹnu kọmisanna feto iroyin ati ilanilọyẹ, Abilekọ Bamidele Ademọla-Ọlatẹju nigba to n jabọ abajade ipade olosoosu awọn igbimọ aṣejọba ipinlẹ fawọn oniroyin l’Ọjọbọ, Tọsidee ọsẹ yii.
Ọdun mẹrin sẹyin ni ijọba Akeredolu kọkọ kede pe ko nii si ohun to jọ ipele D mọ ninu eto ọba jijẹ nipinlẹ Ondo, o ni gbogbo awọn ọba alaye e to wa nipele yii loun ti gbe ga si ipele C, ilana yii ni wọn
n ṣamulo lati igba naa titi tijọba fi tun ṣeto igbega mi-in laarin awọn lọbalọba.
Awọn ọba mẹtalelọgọrin ti wọn gba igbega lati ipele B si ipele A to ga julọ la ti ri.
Nijọba ibilẹ Ariwa Iwọ-Oorun Akoko :
i. Ọwa-Ale ti Iyọmẹta n’Ikarẹ Akoko.
Ijọba ibilẹ Guusu Iwọ-Oorun Akoko :
i. Alalẹ tilu Akungba Akoko.
Ijọba ibilẹ Ariwa Iwọ-Oorun Akoko :
i. Ajana ti Afa, Oke-Agbe nijọba ibilẹ Ariwa
Ijọba ibilẹ Ariwa Akurẹ :
i. Okiti ti Iju,
ii.Ogbolu ti Ita-Ogbolu ati
iii. Ọlọba tilu Ọba-Ile
Ijọba ibilẹ Ifẹdọrẹ :
i. Alara ti Ilara-Mọkin
ii.Olujarẹ tilu Ijarẹ ati
iii. Ọlọwa ti Igbara-Oke
Ilẹ-Oluji /Oke-Igbo
i. Oluoke ti Oke-Igbo
Ilajẹ
i. Moporure ti Agerige
ii. Eletikan tilu Etikan
Irele
i. Ahaba tilu Ajagba
ii. Odogbo tilu Omi
iii. Larogbo ti Akotogbo
Odigbo
i. Ọrunja ti Odigbo
Okitipupa
i. Halu ti Ode-Aye
ii. Ọrungberuwa tilu Ode-Erinjẹ
Ọwọ
i. Ọjọmọ-Luda ti Ijẹbu-Ọwọ
ii. Olupele ti Ipele
iii. Elemure ti Emure-Ile
Ọsẹ
i. Olumoru ti Imoru
ii. Olute tilu Ute.
Ọlatẹju ni igbagbọ ijọba ni ọkan-o-jọkan awuyewuye to suyọ lori eto ọba jíjẹ lawọn ilu kan nipinlẹ Ondo ni wọn tun yanju lasiko ipade ọhun.
Kọmisanna ọhun fi kun ọrọ rẹ pe wọn tun fẹnu ko nibi ipade olosoosu ọhun lati fiya to tọ labẹ ofin jẹ ẹnikẹni to ba deedee fi ara rẹ sori apere ọba eyi tijọba ko tii fọwọ si iru eyi to n sẹlẹ lọwọ niluu Irele nijọba ibilẹ Irele ati Igodan-Lisa nijọba ibilẹ Okitipupa.
Lara ohun to ni igbimọ ọhun tun sọrọ le lori ni bi ede Yoruba pọnnbele atawọn ede adugbo bii Ikalẹ, Ilajẹ, Ijaw atawọn ede abinibi mi-in yoo ṣe di ṣíṣe amulo lawọn ileesẹ ijọba to wa kaakiri ipinlẹ Ondo.

Leave a Reply