Ọwọ ọlọpaa tẹ ogbologboo adigunjale mẹrin ni Kwara

Akolo ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Kwara, ni awọn afurasi ogbologboo adigunjale mẹrin kan, Bello Baneri, Umaru Shehu, Awalu Umaru ati Mamma Muhammed, ti wọn n gbe ni Aba Fulani, Oro-Ago, nipinlẹ naa wa bayii, Fulani to lọọ ta maaluu ni wọn lọọ da lọna tọwọ fi tẹ wọn.

 

 

Ninu atẹjade kan ti Alukoro ọlọpaa ni Kwara, Ọkasanmi Ajayi, fi sita to tẹ ALAROYE lọwọ l’Ọjọruu, Wẹsidee, lo ti alaye pe lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii, lọwọ tẹ awọn afurasi adigunjale naa ni Oro-Agọ, lẹyin ti Fulani kan, Alaaji Yahaya Ishaku, lagbegbe Aba Ahun, Oro-Agọ, mu ẹsun lọ si teṣan ọlọpaa pe oun ta maaluu ni ẹgbẹrun lọna ẹgbẹta Naira (600,000:00), lọja Kaara niluu Ajasẹ-Ipo, ti awọn adigunjale si da oun lọna nigba toun n dari lọ sile, wọn si gba gbogbo owo naa lọwọ oun ni ogunjọ, oKẹjọ, ọdun yii.

 

 

Ileeṣẹ ọlọpaa ati ẹgbẹ Fulani darandaran (Miyetti Allah), ti ẹka Oro-Agọ, bẹrẹ si ddẹ awọn adigunjale naa, eyi lo okunfa bi ọwọ ṣe tẹ awọn mẹrẹẹrin.

Ọkasanmi ni iwadii fi han pe ọkan ninu awọn afurasi naa, Mamma Mohammed, to ba Alaaji Yahaya gbe maaluu sinu mọto nigba to n lọ si ọja lo gbimọpọ pẹlu awọn adigunjale ẹgbẹ rẹ ti wọn fi lọọ da a lọna, ti wọn si gba gbogbo owo ọwọ rẹ nigba to n dari bọ lati ọja.

 

 

Ọlọpaa ti ri ẹgbẹrun lọna ẹgbẹrin Naira (400,000), gba pada lọwọ awọn afurasi

Kọmisanna ọlọpaa ni Kwara, CP Tuesday Assayomo psc (+),  ti paṣẹ pe ki wọn gbe iwadii iṣẹlẹ naa lọ si ẹka to n ṣe iwadii nipa iwa ọdaran fun ẹkunrerẹ iwadii.

Leave a Reply