Awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu PDP ti wọn n tẹle igbakeji gomina ipinlẹ Ekiti tẹlẹ, Sẹnetọ Abiọdun Olujinmi, ti sọ pe gbogbo ara lawọn fi fara mọ gomina ipinlẹ Ọyọ gẹgẹ bii aṣaaju ẹgbẹ oṣelu naa nilẹ Yoruba, ati pe gbogbo igbesẹ Peter Ayọdele Fayoṣe pata lawọn kẹyin si.
Oloye Sanya Adesua ti i ṣe akọwe ikede fun ẹgbẹ naa, iyẹn awọn PDP ti wọn n ṣe ti Olujinimi, lo sọrọ yii, bẹẹ lo fidi ẹ mulẹ pe ofin ẹgbẹ naa lo sọ Gomina Ṣeyi Makinde di aṣaaju ẹgbẹ yii, niwọn igba to jẹ pe oun nikan ni gomina ti PDP ni nilẹ Yoruba loni-in.
Awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu PDP yii ti sọ pe Makinde nikan lawọn gba ni aṣaaju fun ẹgbẹ oṣelu ọhun bayii, ati pe ohun to yẹ Peter Ayọdele Fayoṣe ni pe ko gba fun Ọlọrun lori ọrọ ọkunrin naa, ko ye da wahala silẹ ninu ẹgbẹ naa, niwọn igba ti oun paapaa ti lo iru anfaani ọhun ri lasiko to fi wa nipo gomina laarin ọdun 2014 si 2018.
Adesua fi kun un pe ki i ṣe gbogbo ọmọ ẹgbẹ oṣelu PDP to wa l’Ekiti lo sọ ọrọ kan tawọn eeyan kan n gbe kiri pe ẹgbẹ oṣelu APC ni Ṣeyi Makinde n ṣiṣẹ fun lati maa fi da PDP ru nilẹ Yoruba.
Bakan naa lo fi kun un pe awọn ko nigbagbọ ninu ohun tawọn eeyan kan n sọ pe Enjinnia Ṣeyi Makinde lo n kowo silẹ lati fi ba awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu PDP kan nipinlẹ Ekiti ati Ọṣun ṣẹjọ lati fi da wahala silẹ gẹgẹ bi awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC ṣe fiṣẹ ọhun ran an.
Wọn ni, awọn to n tẹle Fayoṣe kiri ti wọn pera wọn ni Osoko Political Assembly (OPA), ni wọn n sọ isọkusọ kiri, ati pe ohunkohun ti wọn ba sọ, ki i ṣe gbogbo ọmọ ẹgbẹ oṣelu PDP Ekiti lo sọ ọ, ohun ti Fayoṣe ba fẹ nikan lawọn yẹn n ṣe.