Ibrahim Alagunmu, Ilorin
Titi ti a fi n ko iroyin yii jọ tan, ijọba ko ti i sọ idi pataki to fi yọ ọga agba ileewe olukọni, Kwara College of Education, Ilọrin, Ọjọgbọn Abdulraheem Yusuf, nipo, to si fi Ọmọwe Ahmed Jimọh Ayinla rọpo gẹgẹ bii adele ileewe naa.
Ninu iwe ti gomina fi sọwọ si Ayinla to jẹ igbakeji giwa agba tẹlẹ ni ile ẹkọ naa lo ti pasẹ pe ko maa ṣe akoso ile-ẹkọ naa lọ titi ti wọn yoo fi yan ọga agba tuntun fun ileewe ọhun.