Ọrẹoluwa Adedeji
Aarẹ ilẹ wa tẹlẹ, Dokita Goodluck Jonathan, ti sọ pe oun ko mọ nnkan kan nipa fọọmu ti wọn ra fun oun pe ki oun waa dupo aarẹ lorukọ ẹgbẹ oṣelu APC. Ọkunrin naa ni iwa arifin ni fun awọn kan lati ra fọomu foun lai jẹ ki oun mọ si i. O ni bi oun ba fẹẹ dije, funra oun loun maa bọ sita lati sọ fun awọn eeyan.
Ninu atẹjade kan ti Akọwe iroyin rẹ, Ikechukwu Eze, fọwọ si lalẹ ọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii, lo ti sọ pe Jonathan kọ fọọmu ti wọn ni awọn Fulani darandaran atawọn eeyan wọn kan ni wọn ko miliọnu lọna ọgọrun-un Naira jọ, ti wọn ni awọn gba fọọmu fun un.
Eze ni, ‘‘O ti wa setiigbọ wa pe awọn ẹgbẹ kan ti ra fọọmu fun Dokita Goodluck Ebele Jonathan lati dupo aarẹ lọdun 2023 lorukọ ẹgbẹ oṣelu APC.
‘‘A fẹ ko di mimọ fun yin pe Jonathan ko mọ ohunkohun nipa fọọmu yii, ko si ran ẹnikẹni lati ṣe bẹẹ.
‘‘A fẹ kẹ ẹ mọ pe bi aarẹ ilẹ wa tẹlẹ yii ba fẹẹ dupo aarẹ, yoo jẹ ki gbogbo aye mọ erongba rẹ lori eleyii, ki i ṣe pe yoo waa gba ọna ẹburu lati ṣe bẹẹ.
‘‘Bo tilẹ jẹ pe a mọ riri atilẹyin ọpọlọpọ ẹya kaakiri orileede yii ti wọn n sọ pe ki Jonathan jade lati dupo aarẹ ọdun 2023, a fẹẹ fi da yin loju pe ko ti i yọnda ara rẹ lati ṣe eleyii.
‘‘Rira fọọmu idije lorukọ Dokita Jonathan lai beere boya o fọwọ si i, ti ẹ si mọ ipo to ti di mu lorileede yii tẹlẹ jẹ iwa arifin tabi iwọni-nilẹ. Nidii eyi, a fẹ ki awọn eeyan gbe ọkan kuro nibẹ, ohun ti ko ṣẹlẹ ni.’’
Ọrọ to sọ yii lo pana awuyewuye to ti n lọ latigba ti fọto kan ti jade nirọlẹ ọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii, nibi ti awọn Miyetti Allah, iyẹn ẹgbẹ awọn darandaran atawọn eeyan wọn kan ti jade pe awọn fẹ ki Jonathan waa ṣe aarẹ Naijiria lẹẹkan si i, nidii eyi lawọn ṣe wa lati gba fọọmu fun un.
Oju-ẹsẹ lawọn eeyan ti bẹrẹ si i pariwo pe iwa naa ku diẹ kaato. Wọn ni Jonathan ko figba kan jade ko sọ pe oun ti darapọ mọ ẹgbẹ APC, afi to ba ṣe bẹẹ lẹyin. Yatọ si eyi, wọn ni awọn Hausa-Fulani kan fẹẹ fi ọkunrin naa wọlẹ ni pẹlu ẹbun ojiji ti wọn lawọn fẹẹ fun un.
Ohun to tun wa n kọ awọn eeyan lominu ti wọn fi gbagbọ pe o ṣe e ṣe ki aarẹ tẹlẹ naa mọ nipa ọrọ fọọmu yii ni abẹwo to ṣe si Alaga ẹgbẹ oṣelu APC, Sẹnetọ Abdullahi Adamu, ni ọjọ Iṣẹgun Tusidee, ọsẹ yii, iyẹn ọjọ keji ti wọn gba fọọmu fun un. Wọn ni o ṣee ṣe ko jẹ pe loootọ ni ọkunrin naa n wọna lati dupo aarẹ lorukọ ẹgbẹ APC.