Faith Adebọla
Olori orileede yii lasiko iṣejọba ologun, Ajagun-fẹyinti Yakubu Gowon, ti gba oludije funpo aarẹ lẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party (PDP), Alaaji Atiku Abubakar, ati ẹlẹgbẹ rẹ lẹgbẹ oṣelu Labour Party, Ọgbẹni Peter Obi, ati gbogbo awọn ti wọn ti tẹ pẹpẹ iwe ẹsun ọlọkan-o-jọkan siwaju igbimọ onidaajọ to n gbọ awuyewuye to ba su yọ ninu eto idibo aarẹ, iyẹn Presidential Election Tribunal, pe ki wọn simẹdọ, ki wọn fara balẹ lati jẹ ki awọn adajọ naa ṣiṣẹ wọn bii iṣẹ, ki wọn si fara mọ ibi yoowu ti wọn ba gbe idajọ wọn ka.
Tẹ o ba gbagbe, igbimọ Tiribunal naa ti kede laarin ọsẹ yii pe ọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kẹjọ, oṣu Karun-un yii, lawọn yoo bẹrẹ si i gbọ awọn ẹjọ ti wọn ti to jọ pelemọ siwaju wọn ọhun, ọjọ naa lawọn lọọya olupẹjọ ati olujẹjọ, titi kan awọn ẹlẹrii koowa wọn yoo bẹrẹ awijare ati atotonu wọn.
Amọ, nigba to n sọrọ nibi akanṣe asọye kan ti wọn fi bu ọla fun Adajọ ile-ẹjọ giga ju lọ ilẹ wa kan, Chike Idigbe, eyi to waye lọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ karun-un, oṣu Karun-un yii, niluu Abuja, ni Gowon ti sọ pe:
“Ba a ṣe n fẹ ki orileede yii ni ilọsiwaju, a o gbọdọ gbagbe pe ipa ti ẹka eto idajọ n ko ko ṣee fọwọ rọ sẹyin rara ni, agaga ile-ẹjọ to ga ju lọ, tori nibẹ ni wọn ti n foju ṣunnukun wo awọn idajọ tile-ẹjọ yooku ba gbe kalẹ.
“A gbọdọ jẹ kile-ẹjọ tẹjọ maa n pẹkun si naa ṣe atupalẹ ati ijiroro wọn, ki wọn si ṣepinnu to tọ. Ni tiwa, gẹgẹ bii araalu, a gbọdọ firẹlẹ gba idajọ yoowu ti wọn ba gbe kalẹ, tori ohun tile-ẹjọ giga ju lọ ba sọ labẹ ge. Eyi ṣe koko lasiko ti awuyewuye esi idibo ṣi wa nilẹ bayii. Mo rọ awọn oludije gbogbo lati gba ile-ẹjọ laaye lati ṣiṣẹ wọn bo ṣe yẹ, ka si fara mọ idajọ wọn.
Gẹgẹ bii olori orileede ologun igba kan, mo ti mọ iwulo ẹka eto idajọ tipẹ, tori awọn ni wọn le jẹ kilu toro mini-mini bii omi afowurọ pọn”.
Bakan naa ni baba to ti le lọgọrin ọdun naa rawọ ẹbẹ sawọn adajọ pe o dọwọ wọn o, wọn gbọdọ ṣe ojuṣe wọn doju ami lasiko yii, tori igbesẹ ati idajọ wọn yoo nipa lori aabo ẹmi ati dukia nilẹ wa.