Lẹyin ti Mọjeed ti ọgba ẹwọn de lo tun lọọ ji ọkada mẹrin l’Oṣogbo

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Ọjọ gbogbo ni tole, ọjọ kan bayii ni tolohun lọrọ da fún ọmọkunrin kan, Mojeed Ọlarewaju, tọjọ pẹ to ti máa n ji ọkada ọlọkada gbe, ṣugbọn ti ọwọ tẹ ẹ laipẹ yii. O ti n ka boroboro lakolo awọn ọlọpaa nipinlẹ Ọṣun bayii lori ẹsun ole jija ti wọn fi kan won.

Ọmọ ọdun mọkandinlọgbọn ni Mojeed, a si gbọ pe iṣẹ birikila lo n ṣe tẹlẹ ko too di pe o mu iṣẹ ole jija nibaada.

Gẹgẹ bi atẹjade latodọ Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Oṣun, Yẹmisi Ọpalọla, ṣe wi, awọn araalu ni wọn ta ileeṣẹ ọlọpaa lolobo pe wọn kẹẹfin awọn kan ti wọn n ji ọkada lagbegbe Aliè, ni Oke-Baalẹ, niluu Oṣogbo.

O ni kia lawọn ọlọpaa ẹka to n gbogun ti awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun lọ sibẹ, ti ọwọ si ba Mojeed atawọn ti wọn jọ n ṣiṣẹ.

Ni ti Mojeed, Alaroye gbọ pe ọdun 2021 lo ṣẹṣẹ de lati ọgba ẹwọn Ileefẹ, lori ẹsun ole-jija, bo si ṣe pada de lo tun ẹru rẹ di, to tun bẹrẹ iṣẹ ole pada.

Ọpalọla fi da awọn araalu loju pe ipinlẹ Ọṣun ko ni i rọgbọ fun ẹnikẹni to ba ti n huwa ọdaran, o si parọwa pe kawọn araalu tete maa taṣiiri awọn oniṣẹ ibi lagbegbe wọn.

Leave a Reply