Ki i ṣe ojuṣe ijọba lati pese iṣẹ faraalu o – Fẹmi Adeṣina

Faith Adebọla

Oludamọran pataki si Aarẹ Muhammadu Buhari lori eto iroyin ati ikede, Ọgbẹni Fẹmi Adeṣina, ti sọ pe kawọn ti wọn fẹẹ maa bẹnu atẹ lu iṣakoso ọga rẹ, lori airiṣẹṣẹ ati aisi iṣẹ lode yii, tete yaa ṣe ẹnu wọn ni deede ṣibi, o ni ki wọn ma gbe ẹnu nigbekuugbe si ijọba Buhari, ki wọn ma si di ẹbi ti ki i ṣe tiẹ ru u rara, tori lori ọrọ ipese iṣẹ, ki i ṣe ojuṣe ijọba ni lati pese iṣẹ, oun o si le ranti pe Buhari ṣadehun lati pese iṣẹ fawọn ọmọ Naijiria nibi kankan lasiko ipolongo ibo rẹ.

Adeṣina ni ohun to jẹ ojuṣe ijọba ni lati pese aaye ati anfaani to maa mu ki ipese iṣẹ rọrun faraalu, o lawọn olokoowo adani ni wọn ni ojuṣe lati pese iṣẹ, tori ẹ, b’iyọ ko ba dun ọbẹ, kẹnikẹni ma ṣe fikanra mọ ewe rara, lori ọrọ ọhun.

Nibi eto ori tẹlifiṣan ileeṣẹ Arise kan ti wọn ti fọrọ wa a lẹnu wo lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ keji, oṣu Karun-un yii, ni Adifaisa Adeṣina ti sọrọ ọhun.

Nigba ti wọn bi i leere pe njẹ Aarẹ Buhari mu ileri rẹ ṣẹ p’oun aa maa pese iṣẹ miliọnu mẹta faraalu lọdọọdun, Adeṣina fesi pe “Miliọnu mẹta abi kinla, ṣe Buhari ṣadehun iṣẹ miliọnu mẹta nibikibi ṣa? Mi o ro pe wọn darukọ iye iṣẹ kan o. Ohun ti mo ranti pe Aarẹ Buhari sọrọ nipa rẹ ni iye awọn alainiṣẹlẹwọ to wa lorileede yii.

“Mo tun ranti pe wọn sọrọ pato nipa iye iṣẹ ta a n pese, bẹyin naa si ṣe mọ, ọrọ yẹn le wa lati ibikibi.

“Ṣe ẹ ri i, eyi to pọ ju lọ ninu iṣẹ taraalu nilo, ki i ṣe ijọba lo maa pese ẹ tori ki i ṣe ojuṣe ijọba ni lati maa da iṣẹ silẹ kaakiri tabi ko pese iṣẹ, awọn olokoowo aladaani ni wọn maa pese iṣẹ, ohun to jẹ ijọba logun ni lati pese aaye to rọgbọ, ati eto ọrọ-aje to ṣini lori, eyi to maa jẹ kawọn to fẹẹ da iṣẹ silẹ le ṣe bẹẹ ko si ya wọn lara lati ṣe bẹẹ.” Gẹgẹ bo ṣe wi.

Lopin ọrọ rẹ, Adeṣina lu Buhari ati iṣejọba rẹ lọgọ ẹnu, o ni ijọba Buhari fakọ yọ ni gbogbo ọna, titi kan ẹka ipese epo rọbi ati gaasi, ipese awọn ohun amayedẹrun faraalu, lori ẹka ti ofin ati awọn aṣofin, bẹẹ si nijọba ọhun ko kẹrẹ rara lori ipese aabo, o ni ijọba to n kogba sile lọ yii yẹ leyii tawọn araalu gbọdọ patẹwọ fun, tori iṣẹ ni wọn ṣe.

Leave a Reply